-
Notifications
You must be signed in to change notification settings - Fork 7
/
Copy pathYoruba_training_corpus(part).txt
4709 lines (4345 loc) · 806 KB
/
Yoruba_training_corpus(part).txt
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
67
68
69
70
71
72
73
74
75
76
77
78
79
80
81
82
83
84
85
86
87
88
89
90
91
92
93
94
95
96
97
98
99
100
101
102
103
104
105
106
107
108
109
110
111
112
113
114
115
116
117
118
119
120
121
122
123
124
125
126
127
128
129
130
131
132
133
134
135
136
137
138
139
140
141
142
143
144
145
146
147
148
149
150
151
152
153
154
155
156
157
158
159
160
161
162
163
164
165
166
167
168
169
170
171
172
173
174
175
176
177
178
179
180
181
182
183
184
185
186
187
188
189
190
191
192
193
194
195
196
197
198
199
200
201
202
203
204
205
206
207
208
209
210
211
212
213
214
215
216
217
218
219
220
221
222
223
224
225
226
227
228
229
230
231
232
233
234
235
236
237
238
239
240
241
242
243
244
245
246
247
248
249
250
251
252
253
254
255
256
257
258
259
260
261
262
263
264
265
266
267
268
269
270
271
272
273
274
275
276
277
278
279
280
281
282
283
284
285
286
287
288
289
290
291
292
293
294
295
296
297
298
299
300
301
302
303
304
305
306
307
308
309
310
311
312
313
314
315
316
317
318
319
320
321
322
323
324
325
326
327
328
329
330
331
332
333
334
335
336
337
338
339
340
341
342
343
344
345
346
347
348
349
350
351
352
353
354
355
356
357
358
359
360
361
362
363
364
365
366
367
368
369
370
371
372
373
374
375
376
377
378
379
380
381
382
383
384
385
386
387
388
389
390
391
392
393
394
395
396
397
398
399
400
401
402
403
404
405
406
407
408
409
410
411
412
413
414
415
416
417
418
419
420
421
422
423
424
425
426
427
428
429
430
431
432
433
434
435
436
437
438
439
440
441
442
443
444
445
446
447
448
449
450
451
452
453
454
455
456
457
458
459
460
461
462
463
464
465
466
467
468
469
470
471
472
473
474
475
476
477
478
479
480
481
482
483
484
485
486
487
488
489
490
491
492
493
494
495
496
497
498
499
500
501
502
503
504
505
506
507
508
509
510
511
512
513
514
515
516
517
518
519
520
521
522
523
524
525
526
527
528
529
530
531
532
533
534
535
536
537
538
539
540
541
542
543
544
545
546
547
548
549
550
551
552
553
554
555
556
557
558
559
560
561
562
563
564
565
566
567
568
569
570
571
572
573
574
575
576
577
578
579
580
581
582
583
584
585
586
587
588
589
590
591
592
593
594
595
596
597
598
599
600
601
602
603
604
605
606
607
608
609
610
611
612
613
614
615
616
617
618
619
620
621
622
623
624
625
626
627
628
629
630
631
632
633
634
635
636
637
638
639
640
641
642
643
644
645
646
647
648
649
650
651
652
653
654
655
656
657
658
659
660
661
662
663
664
665
666
667
668
669
670
671
672
673
674
675
676
677
678
679
680
681
682
683
684
685
686
687
688
689
690
691
692
693
694
695
696
697
698
699
700
701
702
703
704
705
706
707
708
709
710
711
712
713
714
715
716
717
718
719
720
721
722
723
724
725
726
727
728
729
730
731
732
733
734
735
736
737
738
739
740
741
742
743
744
745
746
747
748
749
750
751
752
753
754
755
756
757
758
759
760
761
762
763
764
765
766
767
768
769
770
771
772
773
774
775
776
777
778
779
780
781
782
783
784
785
786
787
788
789
790
791
792
793
794
795
796
797
798
799
800
801
802
803
804
805
806
807
808
809
810
811
812
813
814
815
816
817
818
819
820
821
822
823
824
825
826
827
828
829
830
831
832
833
834
835
836
837
838
839
840
841
842
843
844
845
846
847
848
849
850
851
852
853
854
855
856
857
858
859
860
861
862
863
864
865
866
867
868
869
870
871
872
873
874
875
876
877
878
879
880
881
882
883
884
885
886
887
888
889
890
891
892
893
894
895
896
897
898
899
900
901
902
903
904
905
906
907
908
909
910
911
912
913
914
915
916
917
918
919
920
921
922
923
924
925
926
927
928
929
930
931
932
933
934
935
936
937
938
939
940
941
942
943
944
945
946
947
948
949
950
951
952
953
954
955
956
957
958
959
960
961
962
963
964
965
966
967
968
969
970
971
972
973
974
975
976
977
978
979
980
981
982
983
984
985
986
987
988
989
990
991
992
993
994
995
996
997
998
999
1000
ORÍKÌ ORÍLẸ̀ Oǹdó NÍ ÌLÀNÀ
dàńsáákì sábó ọfọ̀ jímosùn òkèlísà àníàní òfútùfẹ́tẹ̀ lọ́kanòjọ̀kan òṣemàwé àti lísà ìlú oǹdó ẹ̀dáèdè tìdí òpómúléró adésanoyè ọlábímtán ṣètúpalẹ̀ abímbọ́lá gbogboǹṣe
ADÉDÈJÌ ADÉNÍKẸ̀Ẹ́ TÓSÌN
APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ
OṢÙ ÈBÌBÌ ỌDÚN
ÌFỌWỌ́SÍ
Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin
ALÀGBÀ ÒKÉWÁNDÉ ỌJỌ́
ALÁBÒÓJÚTÓ
OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́
Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́
OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ
ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ
ÌFISỌRÍ
Mo fi ìwé yìí sọrí ọba àwọn ọba Àìkú Àìsá Atẹ́rẹrẹ káríayé ògbìgbà tí í gba aláìlárá Ẹlẹ́rù níyìn ọba tó ń gba aláìlẹ́ni kan ajípọjọ́ikúdà yaágbóyaájù ọkùnrin ogun Ajagungbadé ọba ìyanu ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin fún dídà tí ó da mi sí dọjọ́ òní
Àti
Àwọn òbí mi ọ̀gbẹ́ni àti ìyáàfin Adédèjì fún akitiyan wọn lórí mi láti le jẹ́ kí ń jẹ́ ènìyàn láyé Ẹ ṣeun
ÌDÚPẸ́
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run awímáyẹhùn òwí bẹ́ẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ Ẹ́kùn ọkọ Fáráò Adúró gbọin gbọin lẹ́yìn aṣòótọ́ Òun ni o rànmọ níṣẹ́ fàyà tì í Ọba tó fún mi ni àṣeyọrí tó lógo nínú ẹ̀kọ́ Òun ló tún mú kí iṣẹ́ ìwádìí mi gúnlẹ̀ láyọ̀
Bákan náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ bàbá àti ìyá mi fún àtìlẹ́yìn sùúrù ìjìyà àti ìtọ́jú wọn lórí mi Ẹ ṣeun púpọ̀ oúnjẹ ọmọ á jiná fúnun yín jẹ ní orúkọ Jésù ẹ kò ni ṣe àṣedànù Ẹni ẹlẹ́ni kò sì ni gbà ṣe yín ṣe
Ọpẹ́ pàtàkì mi tún lọ sọ́dọ̀ alábójútó iṣẹ́ mi ọ̀gbẹ́ni Okewande Olúwọlé Tẹ́wọ́gboyè fún akitiyan wọn láti mú kí iṣẹ́ ìwádìí mi yìí yọrí sí rere Ẹ ṣeun ẹ kú iṣẹ́ mi
Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀gá mi alàgbà Wàlé Rafiu Alàgbà Ọmọlayọ̀ Ògúnlọlá Alàgbà Ọ̀tún Ọ̀mọ̀wé Adéyẹmí èmi kò ní gbàgbé yín Ẹ ṣeun
Ọpẹ́ mi tún lọ sí ọ̀dọ̀ abẹ́nàìmọ̀ mi Akinbinuade
Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi gbogbo Aya Ọlánírègún Jọkẹ́ Adédèjì àti Seun Adèdèjì
Bákan náà mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn akẹgbẹ́ mi gbogbo; mo sì tún dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n yìí Ọláníran Láídé Akínpẹ̀lú Abímbọ́lá Ajíbóyè Ọmọ́wùnmí Tọ́pẹ́ Ràmọ́nù Abíọ́lá Folúkẹ́ Bùsáyọ̀ àti Abíọ́dún
ÀṢAMỌ̀
Nígbà tó jẹ́ wí pé afìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ hàn ni lítíréṣọ̀ kókó ohun tí a gbéyẹ̀wò nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni ewì alohùn Yorùbá láti fa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ yọ Àwùjọ tí iṣẹ́ yìí sì dálé lórí ni àwùjọ ìlú Òndó
Nínú iṣẹ́ yìí oríkì àwọn ọba ìlú Òndó ni a gbé yẹ̀wò oríṣìíríṣìí ọgbọ́n ìwádìí ni a sì ṣe àmúlò rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò le ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ kan bí i ewì láìṣe àmúlò tíọ́rì kan tàbí àtinúdá Tíọ́rì tí a ṣe àmúlò nínú iṣẹ́ yìí ni tíọ́rì Ṣosíọ́lọ́jì lítíréṣọ̀
Bákan náà a ṣe ìgbéléwọn àwọn oríkì ọba ìlú Òndó láti mọ àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí a sì tún fi àwọn oníṣẹ́ akadá tó ń bọ̀ lẹ́yìn ní ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú
ÀTẸ ÀKÓÓNÚ
Àkọlé
Ìfọwọ́sí
Ìfisọrí
Ìdúpẹ́
Àṣamọ̀
Àtẹ Àkóónú
ORÍ KÌÍNÍ
ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ
Ìfáàrà
Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí
Ibi tí ìwádìí gbòròò dé
Ọgbọ́n ìwádìí
Àǹfààní iṣẹ́ ìwádìí yìí
Ètò ìwádìí
ORÍ KEJÌ
AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN
Ìfáàrà
Oríkì ní àwùjọ Yorùbá
Oríkì orílẹ̀
Ìbáṣepọ̀ láàárín oríkì àti lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá mìíràn
Tíọ́rì Tíọ́rì Ìṣàmúlò Tíọ́rì Ìfojúìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀láwùjọ
woiṣẹ́ lítíréṣọ̀
ORÍ KẸ́TA
ÀWÙJỌ TÓ BÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌLÚ Oǹdó
Ìfáàrà
Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Oǹdó
Àlàyé lórí oríkì orílẹ̀ Oǹdó
Oríkì àwọn Ọba kọ̀ọ̀kan
Àwọn ọba tó ti jẹ àti ọdún wọn
Díẹ̀ nínú ìtàn ìgbésí ayé àwọn ọba ìlú Oǹdó
ORÍ KẸ́RIN
FÍFI TÍỌ́RÌ ÌBÁGBÉPỌ̀ ÀWÙJỌ Ṣ`ETÚPA LẸ ÀWỌN
ORÍKÌ ORÍLẸ̀ Oǹdó
Ìfáàrà
Àgbéyẹ̀wò ipa àti ipò àwọn ọba ni ìlú Oǹdó
Ìgbésẹ̀ ìfinijoyè
Ipa àti ipò Oǹdó nípa ogun jíjà
Ipa àti ipò àwọn ọba Òndó gẹ́gẹ́ bí alágbára
Ogun jíjà
Iṣẹ́ òòjọ́ wọn
Ètò ìṣèlú
Ìmúra
ORÍ KARÙNÚN
ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀
Ìfáàrà
Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí yìí
Àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí
Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú
Àgbálọgbábọ̀
Àkójọ orúkọ ìwé
ORÍ KÌÍNÍ
ÌPILẸ̀SẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ
ÌFÁÀRÀ
Náání nàànì náání ohun a ní làá náání ìran aṣẹ́gità ní í náání èèpo igi ìran ọmọ Yorùbá a sí máa náání àṣà wọn
Onírúurú bí aṣọ alágẹmọ a ní àṣà tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ mọ èyí a fi ń dánilárayá bì í orin ìtàn àròsọ àti ewì
Nínú gbogbo iṣẹ́ ìwádìí yìí ewì ni a yàn láàyò Ẹ̀yà ara ewì alohùn ni oríkì wà oríṣìíríṣìí oríkì sí ni ó sí wà Bí oríkì ìnágijẹ bọ̀rọ̀kìnní àníjẹ́ àdájẹ́ oríkì orílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bí a ṣe rí oríkì àwọn ohun ti kì í ṣe ènìyàn ṣùgbọ́n tó jẹ́ ohun abẹ̀mí bí i ẹyẹ ẹranko àti àwọn ohun ọ̀gbìn mìíràn
Nínú iṣẹ́ yìí oríkì ni a ó máa gbẹ́ yẹ̀wò kì í sí i ṣe oríkì àwọn ènìyàn lásán bí kò ṣe oríkì àwọn ọba oríkì àwọn ọba tí a sí ń wí yìí rinlẹ̀ ni àwọn ìlú ilẹ̀ Yorùbá Ó máa ń fi bí ipò oníkálùkú àwọn ìlú wọ̀nyí ló ní ọ̀nà tí wọn ń gbà gbé oríkì kalẹ̀ Bí àpẹẹrẹ àrà ọ̀tọ̀ ní oríkì ọba ni Ọ̀yọ́ Àwọn apohùn ló máa ń kéwì yìí
Bí a ṣe rí ìgbékalẹ̀ oríkì àwọn ọba ìlú Ọ̀yọ́ náà ni ṣe rí ìgbékalẹ̀ oríkì àwọn ọba ìlú Ẹ̀gbá Ìjẹ̀bú Oǹdó láti mọ ètò láti mọ ètò àṣà àti ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀yà yìí ìlú Oǹdó jẹ́ ẹ̀yà Yorùbá ni ijọbá ìwọ̀ oòrùn ní ìpínlẹ̀ Oǹdó ìlú tí wọ́n bá pààlà ní ìlú Ìkálẹ̀ tí òun náà wà ní abẹ́ ijọbá Gúúṣú ìwọ̀ oòrùn ní ìpínlẹ̀ Oǹdó
ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ
Bí kò bá nídìí obìnrin kì í jẹ́ kúmólú Ìdí pàtàkì tí a fi dágbálé iṣẹ́ yìí ni láti ṣàfihàn oríkì gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan pàtàkì nínú ọ̀nà tí a ń gbé àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá ga A wò ó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan pàtàkì tí a fi ń pa ìtàn ìlú mọ́ Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àṣà tí ó rinlẹ̀ ni ìlú Oǹdó Kò sí ilé àdúgbò ọlọ́danni tàbí olóyè tí ó wà ni ìlú Oǹdó lónìí tí kò ni oríkì kan tí ó ń fi orísun àti ìhùwàsí wọn hàn
Àtúpalẹ̀ oríkì yóò fún wá ní àǹfààní láti mọ ibi ti wọn ti ṣè wá iṣẹ́ wọn èèwọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀yà Yorùbá Lọ́nà mìíràn orísun wọn àti ìbátan wọn pẹ̀lú ẹ̀yà àti ìlú mìíràn
IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ
Nínú iṣẹ́ yìí a ṣe àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ ọnà àtinúdá bì i ewì ní pàtàkì jùlọ oríkì láwùjọ Yorùbá Iṣẹ́ yìí tan iná wo oríkì tí a le bá pàdé láwùjọ Yorùbá bí i; oríkì orílẹ̀ àti ti ọba Ṣe okùn kì í gùn kò má ni ibi tí a fàá wà Iṣẹ́ yìí tọpinpin orírun ìlú Oǹdó tí a ń gbéyẹ̀wò ìdílé kọ̀ọ̀kan tó ti jẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ títí di òní
Síwájú sí i a ó ṣe àtúpalẹ̀ oríkì orílẹ̀ ní ìlànà tíọ́rì ìfojú ìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ láwùjọ woiṣẹ́ lítíréṣọ̀
Ní àgbálọgbábọ̀ a ó wo àwọn àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí yìí àti ìmọ̀ràn fún ìlò atọ́ka ọjọ́ iwájú
ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ
Kí èròǹgbà wa lórí ìfojú tíọ́rì ìmọ̀ìbaraẹnigbépọ̀láwùjọwo oríkì orílẹ̀ le di mímú ṣẹ a gbọdọ̀ ṣe àmúlò ọgbọ́n ìwádìí tó kún tó sí múná dóko ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti ọgbọ́n ìwádìí líọ sí yàrá ìkówèépamọ́sí
Ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò jẹ́ ọgbọ́n ìwádìí kan tó ṣe pàtàkì Ṣe bí ọmọdé kò bá ìtàn dandan ni kí ó bá àrọ́bá Ẹ̀rọ agbohùn tí a mọ sí téèpù ni a ó lò láti gba ohun òǹkọ̀wé sílẹ̀ kí a tó lọ sí ọ̀dọ̀ abẹ́nàìmọ̀ a tí kọ́kọ́ ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìbéèrè tó múnádóko tí a ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ Ìdí tí a fi lo ẹ̀rọ agbohùn nínú iṣẹ́ yìí ni kí o bà a lé rọrùn fún wa láti rántí ohùn gbogbo tí a bá gbọ́ lẹ́nu abẹ́nàìmọ̀
Síwájú sí i ọgbọ́n ìṣèwádìí mìíràn ni lílọ sí iyàrá ìkówèépamọ́sí Èyí sí fún wa ní àǹfààní láti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí àwọn onímọ̀ ti ṣe lọ́kanójọ̀kan lórí iṣẹ́ tó jẹ́ mọ́ iṣẹ́ yìí A rí àwọn oríṣìíríṣìí ìwé ti àwọn aṣááju tí kọ Gbogbo ìwọ̀nyí ni yóò ran wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí
ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ
Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò fún wa ní ìmọ̀ tí o gbòòrò nípa iṣẹ́ ọ̀nà àtinúdá Yorùbá ewì ní pàtàkì oríkì Iṣẹ́ ìwádìí yìí wà fún ìgbélárúgẹ àṣà àti iṣẹ́ Yorùbá Ojú abùkù tí àwọn kan fi ń wo ó sì le fi bẹ́ẹ̀ di ohùn ìgbàgbé pátápátá
Bákan náà yóò ṣe àfikún ìmọ̀ nínú oríkì àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá tí a ti mọ tẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí ni láti mu kí àwọn oríkì wọ̀n yìí wà lákọọ̀lẹ̀ yóò sí tún ran wá lọ́wọ́ láti mọ ipa ipò àti ìtàn ìgbé ayé àwọn ọba tó ti jẹ́ ni ìlú Oǹdó
ÈTÒ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ
Orí márùnún niṣẹ́ yóò pín sí orí kìíní ni a ti ṣàlàyé ohun tí ó pilẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí gẹ́gẹ́ bí ìfáàrà ibi ni a ó ti sọ̀rọ̀ lórí èrèdí iṣẹ́ yìí ni a ti wọ́n aáyan àwọn ọ̀mọ̀ràn lórí oríkì níbẹ̀ ni a ti wo ohun tí oríkì orílẹ̀ jẹ́ Bákan náà a o wo ohùn tí àwọn aṣáájú ṣe lórí tíọ́rì ìbaráẹni gbépọ̀láwùjọ
ORÍ KEJÌ
AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN
ÌFÁÀRÀ
Ohun tí orí kejì iṣẹ́ ìwádìí dálé lórí ni aáyan ọ̀mọ̀ràn lórí oríkì láwùjọ Yorùbá Bákan náá ni a ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìbáṣepọ̀ láàárín oríkì àti lítíréṣọ̀ alohùn yòókù a ó sí tún ṣàlàyé kíkún nípa tíọ́rì ìṣàmúlò Tíọ́rì ìmọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀
ORÍKÌ NÍ ÀWÙJỌ YORÙBÁ
Gẹ́gẹ́ bí èrò Ọlábímtán ní Oríkì jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí a fi ń da ẹni tó bá jẹ́ Yorùbá mọ̀
Ó tẹ̀síwájú láti ṣe àgbéyẹ̀wò oríkì àwọn orúkọ àmútọ̀runwá bí í Táyé Ìlọ̀rí Dàda àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Èrò rẹ̀ nípa oríkì orílẹ̀ pé
Ó jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí a fi lè mọ ògidi èdè Yorùbá tó gbámúṣé kún inú oríkì orílẹ̀ fọ́fọ́
Lọ́nà mìíràn ó ní
Oríkì orílẹ̀ ma ń rán wa létí ohun tí àtìrandíran bàbá bàbáńlá ìran kan ṣe nígbà ayé rẹ̀ Ó ń sọ nípa iwa iṣẹ́ àti akitiyan àwọn tí a bí sínú ìran tàbí orílẹ̀ yìí Ó tún rán wa létí ìtàn ìpìlẹ̀ wa láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ irú ènìyàn wo ní àwọn bàbáńlá wa jẹ́?
Ohun tí ó sọ fún wa pé oríkì orílẹ̀ kì í bo àṣírí ìwà ikà tàbí ìwà rere kan tí àwọn ará wọ̀nyí bá hù Fún ìdí èyí oríkì jẹ́ orísun ohun àmúyangàn fún ọmọ abínibí Yorùbá
Láṣebìkan ṣàlàyé pé;
Oríkì ní í sọ ibi tí ènìyàn ti ṣẹ̀ bí wọ́n ti là tó àti oríṣìíríṣìí nǹkan akọni tí wọ́n ṣe gbogbo
Ohun tí Láṣebíkan ń sọ ni pé ọ̀nà kan gbòógì tí a fi lè mọ ènìyàn dunjúdunjú ni nípasẹ̀ oríkì irú ẹní bẹ́ẹ̀ nítorí pé oríkì rẹ̀ yóò túṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀
àti Gbàdàmọ́sí sọ pé oríkì ni
Ohun tí àwọn onímọ̀ méjèèjì yìí ń sọ ni wí pé oríkì ni a fi máa ń ṣàpèjúwe ènìyàn tàbí fi gbóríyìn fún ènìyàn
Adéoyè sọ pé;
A sọ ọmọ ní sọ́de ó sebí sódẹ̀ a sọ ọmọ ní sóbọ̀ ó lọ àjò ó bọ A wá sọ ọmọ ní Sórìnlọ ó lọ sájò kò mọ pé ilé lọmọ ti mú orúkọ ànù lọ?
Kókó ohun tí Adéoyè ń sọ ni pé orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ wí pé àkíyèsí tó gbọnngbọ́n máa ń wà kí a tó sọ ọmọ lórúkọ nítorí ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn ó máa ń ní ipa lórí ọmọ tàbí ẹbí lápapọ̀ bóyá ní èyí tí ó dára tàbí èyí tí kò dára
Ọlátúnjí ṣe àlàyé lẹ́ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa bí oríkì ṣe ṣe pàtàkì tó láwùjọ Yorùbá àti bí ó ṣe jẹ́ ohun èlò tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá kò lè ṣe aláìlò nínú ìṣe ojoojúmọ́ wọn Nínú àkóónú ó sọ báyìí pé;
Oríkì
Oríkì wúlò fún ẹni tí à ń kì nípa ṣíṣe àwọn àbùdá rere tí àwọn Yorùbá kà sí àti ṣíṣe àfẹ́rìí àwọn àbùdá tí kò ṣe é fi yangan
Síwájú sí i nínú iṣẹ́ rẹ̀ kò ṣàì ṣe àlàyé lórí àwọn oríkì orílẹ̀ oríkì ọlọ́danni oríkì àwọn ọba ìlú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Ó sì tún jẹ́ kí a mọ̀ wí pé ọ̀nà tí a ń gba gbé àwọn oríkì yìí kalẹ̀ le yàtọ̀ ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn
Dáramọ́lá àti Jẹ́jẹ́ sọ̀rọ̀ nípa oríkì wọ́n ní;
Oríkì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tí àwọn Yorùbá máa ń fi yin ara wọn tàbí ẹni tí inú wọn bá dùn sí
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kò ní í tán lára ọmọ ọba kó má ku dàńsáákì Ohun tí a rí fà yọ nínú rẹ̀ ni pé kò le burúburú nínú ìgbà oṣùn kí a má fi pa ọmọ lára kò le burúburú fún ọmọ ọba kí ó máa ní oríkì bọ̀rọ̀kìnní
Àríwòye olùṣèwádìi ni pé àwọn Yorùbá a tún máa sọ oríkì àdájẹ́ oríkì orílẹ̀ ọmọ Àríwòye pàtàkì tí a tún rí níbi oríkì orílẹ̀ ni pé ó jẹ́ oríkì kan gbòógì tí ó wà fún ẹ̀dá kan tọkùnrin tobìnrin ni ó sì máa ń ní oríkì orílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá
ORÍKÌ ORÍLẸ̀
Oríkì orílẹ̀ ni oríkì tí a mọ̀ mọ àwọn oríṣìíríṣìí àwọn ìdílé tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá Ohun mìíràn tí a lè pè ní oríkì orílẹ̀ ni oríkì orírun láti ara oríkì orílẹ̀ gbogbo ohun tí a bá fẹ́ mọ̀ nípa ènìyàn ni ó lè jẹyọ
Adéoyè sọ pé ibi tí a bá mọ ọ̀nà dé là á ki ìlú dé Oríkì orílẹ̀ ṣe àfihàn bí ìran kan ṣe bá ìran kejì tan ní ilẹ̀ Yorùbá Ibi tí àwọn ìlú kọ̀ọ̀kan ti ṣẹ̀ pàtàkì púpọ̀ nítorí pé ó máa ń ṣe àfihàn bí ìran kan ṣe bá ìran kejì tan ní ilẹ̀ Yorùbá Ibi tí àwọn ìran kọ̀ọ̀kan ti ṣẹ̀ iṣẹ́ ìdílé ni ó lè jẹ jáde Bí àpẹẹrẹ nínú oríkì ọkọ̀ ni a ti gbọ́ pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹyẹ ẹ̀gà gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó máa ń fara hàn nínú oríkì orílẹ̀
Pàtàkì ni oríkì orílẹ̀ láwùjọ Yorùbá kò sí ìlú kan nílẹ̀ Yorùbá tí kò ní oríkì orílẹ̀ Àpẹẹrẹ bí ìhùwàsí ìlú ṣe lè jáde nínú oríkì ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú oríkì ìlú Ìbàdàn pé;
Ìbàdàn ọmọ ajoròsùn
Ọmọ afìkarahun fóri mu
Ìbàdàn ibi olè gbé ń jàre olóhun
Ẹni tí kò bá gbọ́ àlàyé ọ̀rọ̀ yìí á lérò pé Ìbàdàn ń fara kín olè ni ṣùgbọ́n ohun tí ó ń ṣe ni pé Ìbàdàn a máa bá ẹni tí ó bá jáfara pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ wí
Yàtọ̀ sí èyí a tún rí nínú oríkì orílẹ̀ ìlú Oǹdó pé ènìyàn pàtàkì ni wọ́n ó lọ báyìí pé; Akínbínuadé
Ará ìta Ìjámà
Èkímògún ọmọ aládé igbó
Iyẹ magogo ide mu omi
Ọmọ lílà mẹ̀ríndínlógún ṣẹ̀yẹ
Ohun tí oríkì orílẹ̀ yìí ń tọ́ka sí ni pé kò sí ààyè fún ọ̀lẹ àti ìmẹ́lẹ́ ní ìlú Oǹdó
Níbi yìí ohun tí a rí fàyọ ni pé oríkì orílẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìlú iṣẹ́ àti ìhùwàsí ìlú Gbogbo ìwọ̀nyí a máa jẹ jáde nínú oríkì nígbà tí àríwòye ènìyàn Ìrírí àti ẹni tí ó jẹ́ a máa sábà jẹ jáde nínú oríkì àbísọ àdájẹ́ ìnágijẹ àti bọ̀rọ̀kìnní ṣùgbọ́n gbogbo oríkì pátá ni ó jẹ́ ara àṣà Yorùbá
ÌBÁṢEPỌ̀ LÁÀÁRÍN ORÍKÌ ÀTI LÍTÍRÉṢỌ̀ ALOHÙN YORÙBÁ
MÌÍRÀN
Láì ṣe àníàní ìran Yorùbá lápapọ̀ ló ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n sì máa ń gbé èyí yọ nínú ìṣe wọn Èyí ló sún wa dé ibi lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ lítíréṣọ̀ alohùn jẹ́ iṣẹ́ ọnà tó ń ti ìran kan dé ìran kejì Kò sí ní àkọsílẹ̀ rárá Èyí ló bí òwe Yorùbá kan tó sọ pé ṣáájú kí àgbàdo tó dáyé ni adìyẹ ti ní ohun tí ó ń jẹ Fún ìdí èyí kí àwọn Òyìnbó aláwọ̀ funfun tó dé ni àwọn ìran Yorùbá ti ní ohun tí wọ́n ń pè ní lítíréṣọ̀ ti wọn Èyí sì ni lítíréṣọ̀ alohùn
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni a lè gbà rí lítíréṣọ̀ mìíràn ti máa ń bá oríkì pàdé Ìdí ni pé wọn jọ máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wọn Gbogbo wọn ni ó ń lo oríkì wọ́n kì í ya ara wọn nígbà kankan bí ti í wù ó mọ nítorí pé wọ́n ní ìbáṣepọ̀ pẹ́kípẹ́kí Àpẹẹrẹ díẹ̀ lára àwọn ewì Yorùbá mìíràn tí a ń bá oríkì pàdé ni ìjálá Ẹkùn ìyàwó rárà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
Lára lára àwọn onímọ̀ tó ṣiṣẹ́ lórí ìjálá ni Yémiítàn ó sọ pé;
Ìjálá ni àwọn ọdẹ fi máa ń sọ ìtàn oríṣìíríṣìí nípa ògún tàbí nípa ọdẹ ṣíṣe àti gbogbo ohun tí ọdẹ ń fojú rí nínú igbó
Onímọ̀ mìíràn tó tún ṣiṣẹ́ lórí ìjálá ni Babalọlá nínú rẹ̀ ó sọ pé;
Ìjálá ni ewì tí ògún máa lò ní ìgbà ayé rẹ̀
Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ìjálá ní í ṣe pẹ̀lú ògún ní gbogbo ọ̀nà ó jọ ẹni pé àwọn tí wọ́n bá ti ni nǹkan án ṣe pẹ̀lú ògún ni wọ́n máa ń sun ún ìjálá tọkùnrin tobìnrin ló máa ń fi ṣiṣẹ́ ṣe tí àwọn obìnrin sì máa ń sùnun lọ́ọ̀dẹ̀ wọn láti fi dárayá Àwọn tí ó jẹ́ àgbàtẹrù rẹ ganan ni àwọn ọdẹ Àwọn ọdẹ ló ni ìjálá láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wa Wọ́n sí máa ki ògún báyìí;
Ògún torí obì o jẹkùú Ìjẹ̀ṣà
Ogun jà wọ́n ogun ò kẹ́rù wọn
Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ ṣáájú wọ́n tún máa ń ki oríkì ẹranko látàrí iṣẹ́ tí wọn ń ṣe tàbí nípa ìhùwàsí wọn Àpẹẹrẹ ni oríkì Ẹtu
Ẹtu lárún
Ọ̀bẹ̀jẹ́ ń yẹkẹ
Abitete ológún ẹni fa
Abiìjànjá í pe alàárù tantan
Ẹtu mọ́ṣalá Ẹtu sàlàkọ́
Òfèfènfe ari ru tún raṣọ níwájú ọkọ
Oríkì òkè yìí ń ṣe àlàyé bí Ẹtu ṣe rí ni Ẹtu jẹ́ ẹranko tí kò tóbi ṣùgbọ́n tí àwọ̀ ara rẹ̀ máa ń dán bọ̀lọ̀jọ̀ ó sì tún jẹ́ ẹni tí ó máa ń sare ó ní irun lára Ó sì tún jẹ́ ẹranko tí ó ní afínjú púpọ̀ ìjálá aré ọdẹ láti ọwọ́ Yémiítàn Bákan náà oríkì òkè yìí ń ṣe àlàyé bí ó ṣe rí
Ọ̀kan lára àwọn ewì alohùn Yorùbá tí a ń rán lẹ́nu ni ìjálá èyí ni a mọ̀ sí Ìsàré Èyí tí ó túmọ̀ sí pé ọ̀nà ìgbéjáde rẹ̀ ni a fi sọ wọ́n lórúkọ
Babalọlá ti ṣe onírúurú ìwádìí àkójọpọ̀ àti ìtúpalẹ̀ lórí ìjálá ohun tó farasin nínú ìjálá ni ìrèmọ̀jé Àwọn ọdẹ àti àwọn olùsin òrìṣà Ògún ló ni ìjálá Ìjálá sísun máa ń wáyé lásìkò tí àwọn ọdẹ bá ní ètò pàtàkì ṣe Ó lè jẹ́ àjọ̀dún ọdẹ tàbí lásìkò tí wọ́n bá ń bọ òrìṣà Ògún Ìjálá sísun kún fún oríṣìíríṣìí èròǹgbà lítíréṣọ̀ Òun náà sí máa fi àwùjọ Yorùbá hàn dénúdénú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà
Dáramọ́lá àti Jẹ́jẹ́ sọ pé ìjálá kò ṣe fọ sí wẹ́wẹ́ láti fún ni ìtumọ̀ kan pàtó fún ọ̀rọ̀ tí a mọ̀ sí ìjálá
Àwọn ọdẹ a máa dẹ ìgbẹ́ àdẹpọ̀ láti pa ẹran bóyá nígbà tí ẹnìkan nínú wọn bá ni ohun pàtàkì láti ṣe lásìkò ọdún ọdẹ tàbí ọdún ògún bí wọn bá pa ẹran tán nínú igbó Wọn a kó ara wọn jọ láti máa jó àti láti máa fi ìdùnnú wọn hàn Wọ́n a máa gbóríyìn fún orìṣà ògún pé ó mú kí ọwọ́ wọn yá Wọ́n a sí máa fi bí agbára ọdẹ ṣíṣe wọn ṣe ga tó hàn Wọ́n a kí ọdẹ aperin sí erin pípa Wọn a kí ọdẹ apẹkùn sí ẹkùn pípa pẹ̀lú Wọ́n a bẹ̀rẹ̀ ìlù àti ijó láti inú igbó títí wọn a fi dé àrín ìlú bí wọ́n ti ń jó bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa yín bọn fún òrìṣà ògún
Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni a lè gbà pín ewì Yorùbá lọ́nà kan a lè fi ojú ìlò wo ó Èyí ni àwọn ewì tó jẹ́ ti gbogbogbò tàbí tí ó jẹ́ ti àwùjọ Yorùbá lápapọ̀ bí í ìjálá ìwé tàbí ẹ̀ṣà egúngún ekún ìyàwó rárá òkú pípè òwe ọfọ̀ òkú pípè òwe ọfọ̀ eṣe ifá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bákan náà ni àwọn kan wà tí ó jẹ́ ti àdúgbò lára wọn ni
Alámọ̀ Èkìtì orin ọpa Ìgbómìnà olele ijẹ̀ṣà orin etíyẹrí Ègè Ẹgbá
Lọ́nà mìíràn a lè fi ọ̀nà ìgbé jáde pín ewì Yorùbá sí ìsọ̀rí tí a bá ṣe èyí a lè tọ́ka sí ìsọ̀rí wọ̀nyí Ajẹ́mọrọ ẹnu àpẹẹrẹ oríkì ọfọ̀ òwe àlọ́ àpamọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
Bákan náà ni a tún rí àwọn ewì tí a ń rán lẹ́nu tí wọn kọjá ọ̀rẹ́ ṣíṣọ pọ́ńbélé àpẹẹrẹ rárà yùngbà IwìẸ̀sà egúngún ìjálá ìrèmọ̀jé ìyẹ̀rẹ́Ifá òkúpípè àti àwọn tí o jẹ́ ti àdúgbò bí i olele àdàmọ́ olúngbé òsàré ipè ọpa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
TÍỌ́RÌ
Yorùbá bọ wọn ni a kì í sòòṣà lódò kí làbẹlàbẹ̀ mọ́ mọ̀ A kò le ṣe àgbéyẹ̀wò tàbí ṣe iṣẹ́ lámèyítọ́ láì ṣe àmúlò ìlànà kan Ìlànà kan tí a ṣe àmúlò láti sọ nípa tíọ́rì
Adéyẹmí sọ pé tíọ́rì ni abẹfẹ́lẹ́ ìmọ̀ tí a fi ń la ìfun àti ẹ̀dọ̀ onírúurú iṣẹ́ Ó sọ síwájú sí i pé nínú ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì ni tíọ́rì tí jẹyọ àti pé ìwádìí yòówù ti kò bá gùnlé tíọ́rì kan nínú iṣẹ́ rẹ̀ irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ òfútùfẹ́tẹ̀ ni Ó tún fi kúnun pé tíọ́rì náà tún tí ìlànà kan tí a ti dánwò tí a sì rí i pé ó jẹ́ òótọ́ bákan náà
Ọbafẹ́mi sọ pé
Tíọ́rì ni irinṣẹ́ ìmọ̀ nípa ẹwà lítíréṣọ̀ láti jẹ́ kí ìbáṣepọ̀ ó wà láàárín ìran òǹkọ̀wé ìmọ̀ọ́nṣe rẹ̀ àti ìbánisọ̀rọ̀ tó péye
Ohun tí Ọbafẹ́mi ń sọ ni pé àwọn ohun èlò fún àlàyé lórí iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ni tíọ́rì jẹ́
sọ báyìí pé
Tíọ́rì ni lámèyítọ́ tí a ṣe lórí lámèyítọ́ kí iṣẹ́ lámèyítọ́ lè tẹ̀síwàjú
Ọmọniyì ki tíọ́rì báyìí
Ìlànà tí à ń tẹ̀lé láti ṣe ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ òun ní o dúró bí ìránṣẹ́ tí a ń lò fún ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀
Ohun tí Ọmọniyì náà ń sọ ni pé láìsí tíọ́rì agogo ẹnu lásán ni a máa lù lórí ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀
Ọ̀wọ́ méjì ni tíọ́rì yìí pín sí ọ̀wọ́ kìíní rí tíọ́rì lítíréṣọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí kò ni àjọṣe pẹ̀lú òǹkọ̀wé àwùjọ ni èyí tí ó jẹ́ pé a kò le ya lítíréṣọ̀ kúrò lára àwùjọ Ìpín kejì yìí ni tíọ́rì tí a fẹ́ ṣe àmúlò nínú Iṣẹ́ àkànṣe yìí ìyẹn tíọ́rì ìfojúìmọ̀ìbáraẹnigbépọ̀ wo iṣẹ́ lítíréṣọ̀
TÍỌ́RÌ ÌFOJÚÌMỌ̀ÌBÁRAẸNIGBÉPỌ̀LÁWÙJỌ WO IṢẸ́ LÍTÍRÉṢỌ̀
Láì ṣe àníàní ó ṣòro kí a tó lè rí oríkì gbé e tán fún Soṣíọ́lọ́jì ṣùgbọ́n ohun tó jẹ mọ́ ìbáṣẹpọ̀ láàárín wọn ìrírí àwọn ènìyàn láwùjọ ni ohun tí irú ìrírí àti àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fà bá ẹ̀dá Soṣíọ́lọ́jì ni ènìyàn àwùjọ àti ìbágbépọ̀ wọn àti ipa tí irú ìbágbépọ̀ bẹ́ẹ̀ ní lórí àwùjọ
Ó sọ síwájú sí i pé ohun tó jẹ Soṣíọ́lọ́jì lógún jù ni ìgbéayé ẹ̀dá ìwà rẹ̀ èdè rẹ̀ tí ó jẹ òpómúléró fún ìdúró ẹ̀dá láyé nínú èròǹgbà Soṣíọ́lọ́jì ni láti dáhùn àwọn ìbéèrè bí i Báwo ni àwùjọ ṣe ṣe? Báwo ló ṣe ń ṣiṣẹ́? Kíló fa ìdúró àwùjọ? Kí èyí tó lè ṣe è ṣe ìgbéléwọ̀n a máa wáyé lórí ètò àwùjọ ètò ọrọ̀ ajé ètò ìṣèlú àti àwọn nǹkan mìíràn tí ó parapọ̀ jẹ́ ètò àwùjọ
Ohun mìíràn tó tún jẹ Soṣíọ́lọ́jì lógún ni ọ̀nà ìkọ́ni àwùjọ ìfòye àṣà kọ́mọlẹ́kọ̀ọ́ àti bí oníkalukú bí i ọba àgbà àgbà àti ọdẹ ìlú lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe ń gba ipa ti yóò kó láwùjọ kí ìlú ba à lè tòrò
Onímọ̀ mìíràn tó tún ki Soṣíọ́lọ́jì ni ó sọ báyìí pé
Nígbà kan rí àwọn ènìyàn a máa bára wọn ṣe nǹkan pọ Ìmọ̀ nípa ìbára ẹni ṣe pọ̀ yìí
Ohun tí ń wí ni pé ìmọ̀ nípa ìbáṣepọ̀ láwùjọ àwọn ènìyàn ni Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìmọ̀ ìbáragbépọ̀ nìkan ni Soṣíọ́lọ́jì dúró lé ó tún máa ń ṣe ìwòye onírúurú ìyípadà tí ó dé bá àwùjọ Àwùjọ lè rọra máa yí padà tàbí kí o yí padà wìrìwìrì gbogbo èyí ni Soṣíọ́lọ́jì ma ń ṣe ìwádìí rẹ̀
Bákan náà Bísí Ògúnṣínà ki Soṣíọ́lọ́jì báyìí pé
Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ àhunpọ̀ nǹkan méjì Soṣíọ́lọ́jì jẹ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìbákẹ̀gbẹ́pọ̀ tí ó ní ìbáṣepọ̀ àti ìgbẹ̀yìn fún ohun tí ó ní ìyípadà pẹ̀lú àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn látàrí ìbáṣepọ̀ tí wọ́n ni sí ara wọn Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ ìbákẹ̀gbẹ́pọ̀ yòókù
Ohun tí ó jẹ́ Soṣíọ́lọ́jì lógún ni ìgbé ayé ẹ̀dá pẹ̀lú ìrírí ẹ̀dá ẹ̀dá pẹ̀lú àwọn tó ń tẹ̀lé wọ́n Ṣùgbọ́n ohun tó jẹ́ ajólórí Soṣíọ́lọ́jì ni àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn inú àwùjọ
Ọ̀kan lára àṣà Yorùbá ni oríkì jẹ́ ìdí nìyí tí a fi lo tíọ́rì yìí fún ṣíṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí iṣẹ́ àti ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn àti ohun tí ènìyàn ń ṣe ni àwùjọ ní o wa nínú oríkì tí a sì ń fi èdè tí ó dùn gbé e jáde Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ pé èdè tó dùn náà ni òpómúléró àṣà àti wí pé àṣà oríkì àti èdè tí a ń lò fi gbé e jáde inú àwùjọ ni gbogbo wọn tí jẹ́ jáde Èyí ni o mú kí a gbé àtúpalẹ̀ oríkì yìí ka orí tíọ́rì ìfojúìbágbépọ̀ àwùjọ wo lítíréṣọ̀ Èyí yóò sí jẹ́ kí a tún ètò àti àṣà ìbá gbẹ́pọ̀ àwùjọ ìlú Oǹdó sí ìta
Ní àfikún ohun tí a ń sọ ni pé inú àwùjọ kan náà ni ènìyàn èdè àti àṣà tí jẹ́ jáde wọ́n sí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ara wọn Yálà àṣà ilẹ̀ wa tàbí àṣà àtọ̀húnrìnwá àti àwọn aláṣà fúnra wọn Inú àwùjọ náà ni gbogbo wọn tí wá Kò sí àwùjọ kan tí kò ni àṣà àti iṣẹ́ tí ó ń gùnlé Ìdí nìyí tí a ṣe rí oríkì láti ara àṣà Yorùbá tí àwọn ìran Yorùbá lápapọ̀ sí ń gbé e lárugẹ ní gbogbo ìgbà
Àtọba àtìjòyè àtọmọdé àtàgbà tó jẹ́ ìran tàbí ẹ̀yà Yorùbá pátá ni wọ́n ni oríkì tí wọn yálà ti àbísọ tàbí ti orílẹ̀ tó jẹ́ tí gbogbogbò tí ó sì jẹ́ pé inú àwùjọ ni gbogbo wọn tí wá tí ìbáṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn sí wà láàárín wọn
Ní àwùjọ ìlú Oǹdó tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìlú ilẹ̀ Yorùbá àwọn ẹ̀yà Yorùbá náà ló sí wá níbẹ̀ Àwọn àṣà tí a mọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ibẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mo àwọn ìlú ilẹ̀ Yorùbá fẹ́ràn oríkì nínú lítíréṣọ̀ alohùn wọn Wọn a máa lò ó níbi ayẹyẹ tí wọn bá ń ṣe Bí àpẹẹrẹ níbi ìkọ́mọjáde ìṣìlè ìgbéyàwó ìfinijoyé ìsìnkú tàbí lásìkò àwọn ọdún ìbílẹ̀ wọn gbogbo
Oríkì yìí máa ń jẹ́ kí a ni ìmọ̀ nípa ẹní tí o ni oríkì gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú A ó mọ orírun àwọn babańlá rẹ̀ àti àwọn nǹkan akọni mìíràn tí wọ́n tí gbé ṣe nínú ìran wọn Bákan náà ó máa ń fi iṣẹ́ òòjọ́ àmúyẹ àti àléébù wọn hàn Bí a ṣe lè fi ṣe kóríyá fún ènìyàn Gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rí ni àwọn àwùjọ Yorùbá yòókù pátá náà ni ti àwùjọ ìlú Oǹdó ṣe rí
MÁÀPÙ ÌPÍNLẸ̀ Oǹdó
ORÍ KẸ́TA
ÀWÙJỌ TÓ BÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ÌLÚ Oǹdó
ÌFÁÀRÀ
Ní orí kẹ́ta iṣẹ́ iwadiii yìí ni a o ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọba tó tí jẹ́ ètò ìṣèlú wọn Àti àwọn ètò mìíràn tí ó ń mú ìlú Oǹdó yọ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ti i yọ ju orí lọ láàárín àwọn ìlú mìíràn
ÌTÀN ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ ÌLÚ Oǹdó
Ìlú Oǹdó jẹ́ ẹ̀yà Yorùbá ni ìjọba ìwọ oòrùn ni ìpínlẹ̀ Oǹdó ìlú tí wọ́n sí bà pààlà ni ìlú Ìkálẹ̀ tí òun náà wà ní abẹ́ ìjọba Gúúṣù ìwọ oorun ni ìpínlẹ̀ Oǹdó
Ní ayé àtijọ́ àwọn ènìyàn rí ìbejì gẹ́gẹ́ bí àmì burúkú wọ́n sí máa ń pa wọ́n lójú ẹṣẹ̀ tí wọ́n bá ti bí wọn Ní ayé ìgbà náà ọ̀kan lára ìyàwó Aláàfin Ọ̀yọ́ bí ìbejì ṣùgbọ́n ọba yìí nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ púpọ̀ Èyí ló mú kí ó gbìyànjú láti dáàbò bo ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ nípa rírán wọn kúrò láàárín ìlú lọ sí ibi tó jìnnà nígbà tí wọ́n fẹ́ máa lọ sí ìrin àjò yìí Aláàfin fún wọn ni ẹrú àti àwọn nǹkan mìíràn
Ìtàn sọ fún wá pé nígbà tí wọ́n dé IléÌfẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà wọn Ọba Ọọ̀ni ṣe àdúrà fún wọn ó sí kọ àwọn ọmọ wọ̀nyí ni ilà kí o bà le fi dá wọn mọ̀ Wọ́n tẹ̀síwàjú nínú ìrìn àjò wọn Wọ́n de ibi kan tí a ń pé ní ita ìjámà láti ibẹ̀ wọ́n dé Ẹ̀pẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olórí ìlú yìí sí tẹ́wọ́ gbà wọn
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ni wa ibi kan tí a mọ̀ sí Ilẹ̀Olújìí a fi ìgbà tí ó parí sí òkè kan ni Oǹdó tí a mọ sí Òkè Àgunlà Bí wọn ṣe débi òkè yìí wọ́n rí èéfín wọ́n sí tẹ̀lé ipa ọ̀nà yìí wọ́n pàdé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹkiri ọkùnrin yìí gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ ó sì mú wọn lọ sí ibi kan tí a pé ni ìjọré ni ìlú Oǹdó Àwọn ènìyàn ìlú Oǹdó fi ọ̀kan nínú àwọn ìbejì yìí jé ọba àkọ́kọ́ wọ́n sí ń gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn
Bákan náà ni a tún rí ètò ìṣèlú ìlú Oǹdó Ní ilé Yorùbá ọ̀nà tí wọn tí ó jé pé ọba ni aláàkóṣo ohun gbogbo ohun tí ó dájú ni wí pé igi kan kì í dá igbó ṣe Èyí ni wí pé ni inú àwùjọ kì í ṣe ọba nìkan ni ó máa ń dá àkóso ìlú ṣe ó pọn dandan kí àwọn ìjòyè jé amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tàbí alábàá ṣíṣe pọ̀ pẹ̀lú ọba
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ takuntakun ni àwọn ọba àti ìjòyè tó ti jẹ ní ìlú yìí tí gbé ṣe láti rí i wí pé ìlọsíwájú tàbí ìdàgbàsókè dé bá ìlú Oǹdó Nínú gbogbo ẹ̀dá kan ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run Yorùbá jẹ́ ẹ̀dá kan tí o kórìra ìwà ọ̀lẹ àti ìmẹ́lẹ́ wọn Yorùbá gbà pé iṣẹ́ ni oògùn iṣẹ́ wọ́n a máa sọ pé òṣùpá wù mi ju òkùnkùn ẹni tí ń ṣiṣẹ́ wùmí ju ọ̀le àti pé aríṣẹ́máṣe ní í sán fùrọ̀ lóògùn Ìgbàgbọ́ Yorùbá sì ni pé ènìyàn kò lè mú iṣẹ́ jẹ kí ó sì mú ìṣẹ́ jẹ àti pé àgbàlagbà tí ó bá ń la igi tà ó ti sinmi rẹ̀ léwe ni ẹ̀dá tí kò bà sì ṣiṣẹ́ yóò jalè
Ní ìlú Oǹdó wọn kì í jí kí wọ́n káwọ̀ gbenú gẹ́gẹ́ bí a ti rí ìwà àti iṣẹ́ wọn Iṣẹ́ ni wọn máa ń múṣe Akíkanjú àti akin ènìyàn ni a mọ àwọn ará Oǹdó Onírúurú iṣẹ́ ni wọ́n sí yàn láàyò ní èyí tí o ń mú kí ìlọsíwájú ó máa bà wọn nínú ìlú náà yálà nínú iṣẹ́ ọdẹ ni tàbí nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ èyí tí ó jẹ́ iṣẹ́ àtìrandíran wọn tí ó sì ń mú kí ètò ọrọ̀ ajé wọn ó máa gbòòrò síwájú sí i tí o sí tún mú ìdàgbàsókè wọ ìlú wọn
Ètò ẹ̀sìn náà kò gbẹ́yìn nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Oǹdó Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá ni pé Olódùmarè ni ó dá ayé tí ó sì tẹ̀ ẹ́ dó Òun náà ló sì dá àwọn ènìyàn síbẹ̀ kí wọ́n sì tún padà wá láti wá jábọ̀ Lẹ́yìn náà àwọn Yorùbá gbà wí pé wọ́n ní láti máa fi orúkọ Olódùmarè sí ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe láyé nítorí pé bí kò bá sí Olódùmarè ni kò le sí ẹ̀dá kankan
Látàrí èyí ní ó ṣe jẹ́ pé kò sí ẹ̀sìn náà ni ilẹ̀ Yorùbá ti àwọn babańlá wa ń sìn tí wọn kì í ki Olódùmarè níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adẹ́dàá aṣẹ̀dá àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí í ó fi àṣẹ sọ̀rọ̀ tí ó sì ń fàṣẹ dáhùn sí onírúurú ìbéèrè ti ẹ̀dá bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀
Ìran Yorùbá lápapọ̀ ló ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ké pe Olódùmarè pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé yóò dá àwọn lóhùn èyí yàtọ̀ ni ìlú sí ìlú ìletò sí ìletò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Irú ìlànà yìí náà ni a rí ní ìlú Oǹdó
Ṣáájú kí ó tó di pé àwọn ẹ̀sìn àjòjì méjèèjì wọ̀lú Oǹdó ni wọ́n tí ó ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ẹ̀sìn wọn; àti irú ìbọ tí wọ́n máa ń jẹ́sìn fún Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ́ pé ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ẹ̀sìn ìbílẹ̀ náà ló wọ́pọ́ ni ayé tí ìdílé kọ̀ọ̀kan nínú ìlú sí ni òrìṣà ìdílé tí wọ́n ń bọ yàtọ̀ sí òrìṣà tó jẹ́ tí gbogboo gbò bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń ṣe ní ìlú Oǹdó yìí láti ayébáyé Àpẹẹrẹ irú ọdún bẹ́ẹ̀ ni ọdún Gbélérù ọdún Ọlọ́kà ọdún Ìta Mafo ọdún Agẹmo ọdún Ògún ọdún Ajé ọdún Ọba ọdún Èkímògún ọdún Atakùnmọ̀ ọdún Ìfọ̀rẹ́ ọdún Olórí ọdún Ọba ọdún Ẹrínlà ọdún Lódún
Ọdún oirì òṣémàwé àti otu ni Àjàlé òkèilé ni agogo mẹ́rin àárọ̀ kò sí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ kí ó tó di àárọ̀ Kété lẹ́yìn èyí ni ẹgbẹ́ òtú yóò máa kúnlẹ̀ fún àdúrà ni ọ̀dọ̀ òṣémàwé ní kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú obìí kọ̀ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òṣémàwé bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ olórí òtu títí kan olóyè kékeré láì ku olóyè kankan A kò sí gbọdọ̀ tan iná Wọn kò sí gbọdọ̀ rí ara wọn Èyí wà fún àdúrà pàtàkì pé ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ọba fẹ́ bẹ̀rẹ̀
Ọdún Ìfòré Ní ìgbà ọdún Ìfòré àwọn olóyè ìlú Oǹdó yóò mú oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn wá fún òṣémàwé Òṣémàwé yóò mú lára àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò gba ìlù fún ayẹyẹ ọdún Àwọn òpójì tí a mọ̀ sí òpò ilé yóò mú ìkájú ẹja ńlá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ obì wà fún òṣémàwé
Lẹ́yìn ọgbọ́n ọjọ́ ọdún Ìfòrè àwọn òpòjì yóò gbé obì lọ fún òṣémàwé ọba yóò gún méjìlélógún pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí àti iṣu tí yóò gbé fún Òyìnbó kan tí a mọ̀ sí olóyè gíga Lisa Lóbùn
ÀLÀYÉ LÓRÍ ORÍKÌ ORÍLẸ̀ Oǹdó
Oríkì orílẹ̀ ní àárín àwọn Yorùbá jé ohun tí o ṣe pàtàkì Oríkì orílẹ̀ ni àpapọ̀ oríkì àwọn babańlá àti àwọn ìyáńlá tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìtàn ìdílé olúwarẹ̀ oríkì orílẹ̀ jẹ́ oríkì tí ó ń júwe ìwà ìṣe babańlá àti ìyáńlá ẹni tí a ń sọ̀rọ̀ bá wọ̀nyí A kò le sọ ní pàtó iye àwọn oríkì orílẹ̀ Yorùbá ṣùgbọ́n àwọn tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú wọn tó mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n kókó ọ̀rọ̀ tó sì wà nínú oríkì orílẹ̀ ni ìwà ọmọlúàbí Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ inú oríkì máa yan ìtàn àtijọ́ àlàyé kíkún yóò sí kù sí ọwọ́ olùwádìí
Ìgbà tí wọ́n bá ń kí ènìyàn ni ọ̀nà pàtàkì ní òwúrọ̀ kùtukùtù bí ọmọ bá ti dòbálẹ̀ tàbí kúnlè láti kí òbí rẹ̀ kú òwúrọ̀ Ìyá yóò lo gbólóhùn mélòó kan láti inú oríkì ìdílé wọn láti fi ki ọmọ náà tàbí nígbà tí ó bá lọ kí ìbátan àwọn òbí rẹ̀ tí kò rí fún ọjọ́ pípẹ́ tí ìbátan náà ba jẹ́ obìnrin gbàrà tí ó bá tí rí ọmọdé náà ni yóò tẹnu bọ oríkì orílẹ̀ wọn; yóò máa fi oríkì orílẹ̀ kí ọmọdé náà lọ bí ilẹ̀ bí ẹní ó le máa dẹ́nu dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti wí pé ó káre ǹlẹ́ o kú àtijọ́ gbogbo àwọn arailé ńkọ́? àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Orí rẹ̀ náà yóò mu ara rẹ̀ a sí yá gágá pẹ̀lú ẹ̀rín múṣẹ́
Bákan náà nígbà tí àgbàlagbà bá ń ṣe àjọyọ̀ ní agboolé rẹ̀ nítorí ohun mìíràn oríkì orílẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n a máa fi kì í
Síwájú sí i a tún rí oríkì orílẹ̀ ìlú Oǹdó pé ènìyàn pàtàkì ni wọ́n ó lọ báyìí pé
Ará ìta ìjámà
Èkímógún ọmọ Aládé igbó
Ọmọ afi agogo idẹ mú omi
Ọmọ onílà mẹ̀ríndínlógún ṣẹ̀yẹ
Bákan náà ni a tún rí àwọn nǹkan to mú oríkì orílẹ̀ Òndó wáyé
Láyé àtijọ́ ogun ni o ya tọkọtaya Ogun ní ó ya ìyá pẹ̀lú ọmọ Bí ọmọdé kò bá sí bá ìtàn ó yẹ kò bá àrọ́bá àrọ́bá sì ni bàbá ìtàn Ogun mú lélé lọ ẹ̀gbá alaké ìyá kò bí lélé ni ẹrú bàbá kò sí sọ ọmọ rẹ̀ ni ìwọ̀fà Àkúnlẹ̀yàn wọn ló tí wọ́n dé ọkọ ẹrú lóko ẹrú tí lélẹ̀ wà Ó múra ṣiṣẹ́ ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lélé ṣiṣẹ́ kára Ó sì ra ẹrú tó pọ̀ Lára ẹrú tí lélè tún rà ni mòrẹ̀ tún wà láì mọ Lélé pa àṣẹ wí pé kí mórẹ̀ máa lọ ògì Ìgbàkugbà tí mórẹ̀ bá tún lọ ògì ni ó máa ń kọrin tí ó bá sí tí ń kọrin yìí ni àwọn ọmọ olówó rẹ̀ ń fi etí gbọ títí wọ́n fi mọ orin náà kọ Wọ́n wa ń kọ orin náà ni ojú bàbá wọn Lélè Lélè gbọ ó ṣe hàá ẹnu ya bí àwọn ọmọ rẹ tí ń kọrin wọ́n ṣe àlàyé wí pé ẹrú titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rà ni o máa ń kọ Lélè wá pé ẹrú o sí bẹ̀rẹ̀ orúkọ rẹ̀ ẹrú sí dáhùn pé Morẹ Lélè wá sọ fún Mòrẹ pé òun ni Lélè àbúrò rẹ̀ mọ̀rẹ̀ náà tún fi hàn wí pé òun ni mọ̀rẹ̀ àti wí pé ìyá wọn ni oólìbàbì Lélè wá pàsẹ wí pé kí àwọn ẹrú tó kù kí wọ́n pọ́n omi kí wọ́n sí wẹ mọ̀rẹ̀ Ìdí pàtàkì tí a fi ń jẹ oríkì ni wí pé kí a lè mọ ibi tí a ti wa tàbí bí a bá sọnù kí a le rí ara wa padà
ORÍKÌ ÀWỌN ỌBA KỌ̀Ọ̀KAN
Ní ìlú Oǹdó yàtọ̀ sí pé àwọn ọba wọn ń jẹ́ oríkì papọ̀ A tún rí díẹ̀ gbà nínú àwọn oríkì bọ̀rọ̀kìnní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn Èyí ni oríkì tí àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ fi máa ń kì wọ́n látàrí ohun ribiribi tí wọ́n tí gbé ṣe àti nípa pé wọ́n jẹ́ akikánjú ènìyàn oríkì bọ̀rọ̀kìnní ọba kọ̀ọ̀kan lọ báyìí ni ṣókí
YÉSÀN
Láte fẹ̀fẹ̀
Onísu to ta gbòngbò
Ìyá ẹní aya aláya ṣe sọ
Ó le eku wọ́nu ẹgàn pátápátá
Ó na aya ẹní túká
Ó bi ọmọ ẹbí ní
Ọjọ́ dínkù ó ṣe tán olósùn ńlá
Ó sùn gàdágbà légbè ọ̀run
Ohun tí oríkì yìí ń sọ nípa rẹ̀ ni pé ọba yìí fẹ́ràn iṣẹ́ ọdẹ láìṣeyeméjì rárá Ó fẹ́ràn láti máa dẹ̀gbẹ́
ORÍKÌ ADÁJÀ
A ń wa
O fi agogo idẹ mọ tí
Eléwù gbòho onikédìgbò
Ó dá títí ọlá
Ó gún le egbò
Òkè Àlejó
Àlajó gba ilé gbé
Ádajà Eléwù gbòho
Orílẹ̀ egbé
Òkè àlejó
ORÍKÌ JOMU
Òyàn onídà
Òyànyán onimú
Ogbogbo létí
Ó ṣe ọwọ́ bàbá núdà
Egún ńlá o
Ó pá ayé run
Ó pa ifọ̀ láyìnmí
Ó pa onígbọ̀wọ́
Ó dà jẹ ẹran mìmìmì
Ó fi ọwọ́ gbọ́ ifá
Ó ń àyé láìláì
Ó dàgbà lọ́dọ̀ èṣù
ORÍKÌ LÓSÙNLÁ
Ajágìgì oògùn
Olókè mẹ́ta
Òkòkò Balógun
Ó dúró lókè
Ó sọmọ di pùyé pùyè
Òkè gbọ́mọ di tilolo
Ologun tí kà di
Odidi mọndè
Ojú ogun láwé sawé
ORÍKÌ LÓGBÒSÉRÉ
Ató àgbà gbọngbọn
Ó kó ẹbí mọ́ra
Ó pàlàngà ẹbí
Ó mú gogo rẹ̀ ṣe
Ó fi pópó nu ojú
ORÍKÌ ARÓGBÓ
Àgbède onígèlè
Ọkọ pupa
Ó lọ sòko
Elétí arógbó
Ọba kú kegun
Elete dèyìn
Olè lébà onílé
Arógbó ilà ṣẹ̀gi
ORÍKÌ LÓYÌNMÍ
Òkè odò
Alájé orùn akingbájìn
Ó ṣe pẹ̀lẹ́
Oní pẹ̀lẹ́
Ajerú mo boku ṣenu
Òrún to Ato
Ató ọba nífẹ̀
Ìgbésí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀
Lóyìnmí aláte ìlèkè
ÀYÀDÌ
Ìyálà lepegun
Ó mú aṣọ ọba
Ó mú idà
Ó fi idà sẹ́yìn
Ó fi idà jẹṣu
Ó sojú kókó
Alálè orò tí
Sun ọmọ ayé jẹ
Àyàdì légbàdà
Ó kò inà léyìn jọyọ
ORÍKÌ ÒṢÉMÀWÉ
Kábíyèsí àbá ìyé
Ikú alaṣẹ
Ògbìgbà gbọmọ là
Ó la lóni o
Ó jìwàjiwa ìlẹ̀kẹ̀
Ó sọkọ àkókó
Alagbára jeni níyà
Afèrín sí
Ikú aláṣẹ èkejì òrìṣà
ORÍKÌ AJISÓWÓ
Ọtún owó
Ọmọ afèrì wọ̀wọ̀
Sọrọ méjì Ajisówó
Ọmọ Lísà pátákó
Aṣọ orúkọ oníbàràká
Òtẹ̀lú òrèrú o fi
Owí erú jọba
Ará ìgúrì
ÀWỌN ỌBA TO TÍ JẸ́ ÀTI ỌDÚN WỌN
Pùpùpù ọdún mẹ́rìnlá
Airo ọdún mọ́kanlélógún
Lújù ọdún mọ́kanlélógún
Òkùta ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n
Lúyaré ọdún mọ́kàndínlógún
Fòyì ọdún mọ́kàndínlógún
Léyò ọdún mọ́kàndínlógún
Gbayi ọdún mẹ́tàdínlógún
Liyen ọdún mẹ́tàdínlógún
Bàjùmú ọdún mẹ́tàdínlógún
Aperuwa ọdún márùnún
Gbede Gbede
Làmolè ọdún márùndínlógún
Aganmede ọdún mọ́kànlá
Olowolaiye ọdún mẹ́tàdínlógún
Jógundè ọdún mọ́kànlá
Térere ọdún mẹ́rindínlógún
Ajímósó ọdún mẹ́rindínlógún
Árobiréré ọdún mẹ́sànán
Ayanlọlá ọdún mẹ́ta
Ọdúnọla ọdún márùnún
Jílù ọdún márùnún
Olówólakun ọdún márùnún
Jíwòmó ọdún méje
Jílàlá ọdún mọ́kànlá
Jímósùn ọdún mẹ́sànán
Afunbiye ọ̀dúndún ọdún méje
Arílékọ́lásì ọdún márùnún
Jímosùn ọdún mẹ́rin
Ọ̀ṣungbádelọlá ọdún mẹ́ta
Ayíbíkíwòdì ọdún márùnún
Afàìdùnóyè ọdún márùnún
Jímẹ́kùn
DÍẸ̀ NÍNÚ ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ỌBA ÌLÚ Oǹdó
Ní ilẹ̀ Yorùbá ní ayé àtijọ́ tí wọn ba tí bí ìbejì wọn a pa wọ́n nítorí abàmì ọmọ ní wọ́n kàásí lásìkò yìí ni wọ́n bí Òsárewásakin ọmọ ọba Olááso ni aláàfin Ọ̀yọ́ ó sí ni ìyàwó púpọ̀ Ó fẹ́ràn ìyá àwọn ọmọ wọ̀nyí kò sí fẹ́ pa wọ́n Ó kó àwọn ìbejì náà pẹ̀lú ìyá ránsẹ́ sí Epinni ni ìlú àwọn Ìbàrìbá Nígbà tí ọba Oluaso tẹ̀rí gbaṣo ní ọba Onígbogí jẹ́ tẹ́lẹ̀
Onígbogí jẹ́ obìnrin tí o jẹ́ ọba ni kò fé kí wọn fi ìyá jẹ wọ́n ó sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ ìjà kí ó kọ wọ́n kúrò ní ìlú gba ọ̀nà IléÌfẹ́ Ìjẹ̀bú ọba Ọọ̀ni sí tún ràn wọ́n lọ́wọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lò tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi de ìlú Ẹ̀pẹ́ Láti ìlú Ẹ̀pẹ́ ni wọ́n tí rin ìrìnàjò wọn dé ibi ìdíèdó pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọmọ náà tó túmọ̀ sí EseOmore títí o fi di Òṣemàwé tí ìdíèdó sí da Oǹdó
Ọba pùpùpù
Gẹ́gẹ́ bi a tí gbọ́ nínú ìtàn pé ìjọba rẹ̀ dára Ó fẹ́ràn àwọn ohun ọ̀sin púpọ̀ gẹ́gẹ́ bi a tí gbọ pé àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ jọ ń ṣe ìpàdé pọ̀ ó kúrò lọ́dọ̀ wọn ó lọ mójútó àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ Irú ìwà yi bí wọn nínú tí wọ́n sí pinnu wí pé àwọn kò ní fi obìnrin jẹ ọba mọ́ ni ìlú Oǹdó
Ọba Airo
Lẹ́yìn ikú ọba Pupupu ni ọba Airo tẹ̀lé ìyá rẹ̀ ó sí kéré nígbà tí ó jẹ́ ọba ṣùgbọ́n Àyàdì lọ ń tọ sọ́nà ó sí ń ba ṣe ìjọba rẹ̀ títí tí o fi le ṣe ìjọba fún ra rẹ̀
Ó dá ẹgbẹ́ Àyàdì àti ẹgbẹ́ òrúnbátó sílẹ̀ ní ọjọ́ kan ó ṣe ìpèdè pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí pààrọ̀ oyè wọn Ó mú Lísà ṣáájú Jomu ó mú ọ̀dunwò ṣáájú sàseré Ó pààrọ gbogbo wọn ó mú ẹni tí ó ṣáájú lọ sí ẹ̀yìn Nítorí ìwà yìí ni àwọn ìgbàanì ṣe ń pè ní Airo ìjọba rẹ̀ sí dára
Ọba Lújù
Nígbà tí ọba Airo tẹ́rí gbaṣọ ni ọba Lújù bọ sí orí ìtẹ́ kò tó di ìgbà tó jẹ ọba ni àwọn baálẹ̀ Yorùbá máa ń lọ bá ọba Ọ̀yọ́ ṣe ọdún tàbí kí wọn rán àwọn oníṣe wọn lọ pẹ̀lú ẹ̀bùn
Kété tí ọba Lújù gún orí oyè ní ó lọ farahàn aláàfin ní Ọ̀yọ́ Nígbà tí ó wà ní Ọ̀yọ́ o fi ojú sí bí ọba Aláàfin tí ṣe kọ́ ààfin rẹ̀ Ọba ají bóyèdé ló wà lórí ìtẹ́ Bí Lújù ṣe tí Ọ̀yọ́ dé ó sọ fún àwọn ará ìlú Oǹdó kí wọ́n kò irú ilé yìí Ogun bẹ́ sílẹ̀ ni ìlú Oǹdó tí o sí ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun jẹ́ kò sí àlàáfíà Ìjà yìí pọ̀ tó jẹ́ pé wọ́n kó lára àwọn Oǹdó lẹ́rú; wọ́n sí ṣẹ́gun àsìkò yìí ni Jomuńlá yọ sí wọn ó pa púpọ̀ nínú wọn
Lẹ́yìn ogun yìí ni ọba Lújù ṣe oògùn fún Oǹdó pé ogun kò ni jà Oǹdó mọ láéláé Ó sí rí igi ẹ̀gún káàkiri ìlú ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe kọ́ ilé sẹ́yin igi yìí Àwọn Oǹdó kò sí kọ́ ilé sí ẹ̀yìn odi ìlú nígbà náà Ọlọ́run sì gbà bẹ́ẹ̀ fún ọba yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀ lásìkò ọba Lújù àwọn ọmọ rẹ̀ ni òkúta Lúyàré Fòyì àti Lẹ́yò
Ọba Lúyàrè
Kò sí ogun tàbí ọ̀tẹ̀ lásìkò tirẹ̀ ọmọ Lújù sí ni Ó sí jẹ́ kí àwọn Oǹdó máa pe ọmọ ìyá kán náà ni gbogbo wọn ó ń ba àwọn Oǹdó kẹ́dùn tí ọfọ̀ bá ṣẹ̀ wọ́n ó sí ní àánú púpọ̀ fún ara ìlú rẹ̀ orúkọ rẹ̀ sí gbilẹ̀ lásìkò tirẹ̀
Ọba Fayi
Ọba alákínkanjú ló jẹ́ ó sí jẹ́ ọmọ ọba lúyàré kí ọba yìí tó jẹ ni àwọn ara ìlú Àmọ̀ná díde ọ̀tẹ̀ tí wọn sí ba ìlú jẹ́ ṣùgbọ́n ó dìde bí akọni ó jẹ́ dódun tí ó bá de ojú ìjà a mú kí òòyì máa kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀ lójú títí o fi gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ ìdí tí wọ́n ṣe ń pé ni ọba Fóyì ni èyí
Ọba Lẹ́yọ̀
Ọba Lẹ́yọ̀ ni o jẹ ọmọkùnrin tí ó kéré jùlọ nínú ọmọ ọba Lújù ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n Ó sí jé ọ̀rẹ́ sí ọba Ayíbí ọba Aláàfin Ọ̀yọ́ ṣe ọ̀rọ̀ ìmùlẹ̀ Nígbàkúùgbà ní ọba yìí ń fi àwọn ọmọ ògún ránṣẹ́ sí í ó sì máa ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀
Ọba Gbàjì
Ọba gbàjì jẹ́ ọmọ ọba òkúta ó kéré nígbà tí ó jẹ́ ọba kò sì olùdádàmọ̀ràn kan fún kò sí gbọ́n púpọ̀ Oǹdó sí rẹ́ ẹ jẹ́ Irú ìwà játi jàti yìí ló mú kí ó máa hu ìwà àíbìkítà sí àwọn Oǹdó kí o tó wá di pé gbogbo rẹ̀ rọlẹ̀ díẹ̀
Ọba Liyen
Ó jẹ́ ọmọ ọba lújù ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ìjẹ̀bú olóògùn ni ọba yìí oríṣìíríṣìí egbògi lò wà lọ́wọ́ rẹ̀ kí o tó wá jẹ ọba Oǹdó sí fẹ́ràn rẹ̀ ó ma ń ṣe oògùn fún aláboyún ọmọdé àti àgbà Kí o tó kúrò ni Ìjẹ̀bú ó mú òrìṣà Ifá àti agẹmọ wá sí Oǹdó lẹ́yìn ìgbà tí ọba yìí tẹ́rí gbaṣọ àwọn ènìyàn fẹ́ràn láti jẹ́ kí ọmọbìnrin kan ṣoṣo tí o ni di òṣémàwé nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ni sí ọba yìí ṣùgbọ́n àwọn Oǹdó tí ṣe ìbúra pé obìnrin kò jẹ ọba ní ìlú Oǹdó mọ́
ORÍ KẸ́RIN
FÍFI TÍỌ́RÌ ÌBÁGBÉPỌ̀ ÀWÙJỌ ṢÈTÚPALẸ̀ ÀWỌN ORÍKÌ ORÍLẸ̀ ÒNDÓ
ÌFÁÀRÀ
Oríkì ṣe pàtàkì láàárin àwọn Yorùbá ó máa ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn nǹkan tí kí bá fi ara sin nípa ẹni tí ó ni oríkì Oríkì jẹ́ ewì gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Oyèrìndé tí ó sọ pé sọ pé ewì alohùn jẹ́ òtítọ́ ju ìtàn lọ Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀ a jẹ́ pé ó sàn kí a ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn oríkì àwọn ọba ìlú Òndó kí a ba le rí kókó kan dì mú nípa àwọn ọba wọ̀nyí Àwọn nǹkan tí ó ṣe pàtàkì tí a lè rí nínú oríkì àwọn ọba ìlú Òndó ni ètò ọrọ̀ajé ìbágbépọ̀ àwùjọ
Bákan náà ni a tún rí àwọn kókó mìíràn bí ìfaradà wọn agbára wọn iṣẹ́ wọn ọgbọ́n wọn ìtàn wọn àti ìwà wọn
ÀGBÉYẸ̀WÒ IPA ÀTI IPÒ ÀWỌN ỌBA NÍ ÌLÚ ÒNDÓ
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ ènìyàn lásán kò le jẹ́ ọba ní ìlú Òndó bí kò ṣe akọni ènìyàn A lè mọ ipa àwọn ọba wọn nípasẹ̀ ìwà akin wọn àti agbára tí wọ́n ní pẹ̀lú
Tí a bá wo ẹni tí ń jẹ ọba ní ìlú Òndó a máa rí i pé olórí ogun ni Èyí fihàn pé a lè mọ ipa àwọn ọba nípasẹ̀ ipò wọn Díẹ̀ nínú àwọn tó jẹ ọba
OYÈ IPÒ
Olóyè Àyàdí Ijámà
Olóyè Òrúnbátó Lótù ìjámà
Olóyè Légírí Líyé majà
Olóyè Àrùwá Láogo Ijámà
Olóyè Lódàsá Itáwuyì Ijámà
Olóyè Lóyìnmi Lójòjò Ijámà
Olóyè Sòkòtí Lotogbe Ijámà
Báyìí ni ipò àwọn olóyè tí ó jẹ́ ọba ní ìlú Oǹdó Àwọn ipò yìí jẹ́ pàtàkì ó sì tún jẹ́ ipò fún àwọn alágbára pẹ̀lú
Ipò àwọn ọba yìí kì í ṣe nǹkan tí a lè fojú tẹ́ńbẹ́lú tí ìlú bá ń dára ó kù sí ọwọ́ ọba tí eku kò bá ké bí eku mọ́ tí ẹyẹ bá ń ké bí ẹyẹ kò ba sì ké bí ẹyẹ mọ́ ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí ọba ni olùdarí ìlú
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ ọba ni olórí ohun gbogbo ipa ọba ni láti pàṣẹ fún ìlú tí àṣẹ náà sì gbọdọ̀ múlẹ̀ Ipa àwọn ọba Oǹdó ni pípa àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ipò tí wọ́n wà Lára àwọn ipa ọba ìlú ni láti to ìlú wọn wọ́n a máa to ìlú kí rúdurùdu má ba à le wáyé èyí sì jẹ́ pàtàkì lára ipa àwọn ọba yìí kí alaafia le bá a jọba ní ìlú Òndó
Bákan náà ni a tún rí àwọn Ìwàrẹ̀fà tí ó ní ipa tí ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ń kó ní ìlú Oǹdó kí ìjọba ó lè rọrùn ní ṣíṣe wọ́n máa ń yan àwọn ìjòyè láàárín ìlú sí àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan tí ìbáṣẹpọ̀ wọn sì máa ń dánmọ́rán Bí àpẹẹrẹ
OYÈ IPÒ
Olóyè Òrúntó wà fún Òkèlísà
Olóyè Arógbó òkè odunwo
Olóyè Lógbòsẹ́rẹ́ ọ̀rérétu
Olóyè Sàsọ̀rẹ odòsídà
Olóyè Jomu Lẹ́gírí ìdí Lẹ́gírí
Bákan náà ni a tún rí àwọn ìgbìmọ̀ olùdámọ̀ràn ọba tí ó j ewì pé ojúṣe wọn ni yíyan ọba sí ipò Ó ní àwọn ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé ní yíyan ọba sí ipò ní ìlú Oǹdó
Lára àwọn olóyè ni ó máa ń kópa nínú àwọn ètùtù ìfijoyè Ìlànà tí wọ́n máa ń lò nìwọ̀nyí
Ì GBÉSẸ̀ ÌFINIJOYÈ ỌBA ÌLÚ ÒNDÓ
ÌGBÉSẸ̀ KÌÍNÍ Àwọn olùránṣẹ́ tí a ń pè ní òdìbò Lísà Jomu òdunwò sàsọrẹ́ àti Adájà ni yóò sin àwọn olóyè àti ṣamọ̀rà lọ sí abúlé láti lọ mú òṣèmàwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn Wọn yóò sọ fún un wí pé wọ́n wá láti wá mu nítorí ìbáṣẹpọ̀ tí ó ní pẹ̀lú ìyàwó olóyè gíga Lísà
Lẹ́yìn tí òṣemàwe tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn bá ti tako ẹ̀sùn yìí ni wọn yóò sọ fún pé àwọn ará ìlú Oǹdó ni ó fẹ́ kí ó jẹ òṣemàwe ti ìlú Oǹdó yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn bẹ́ẹ̀ ni yóò sì ta wọ́n lọ́rẹ ewúrẹ́ kan
ÌGBÉSẸ̀ KEJÌ
Olóyè Lísà sàsọrẹ́ yóò mú òṣèmawé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ sí ilé olóyè Lísà ni òkèlísà ní àdúgbò lákó ní nǹkan bí déédé agogo márùnún àárọ̀ ọjọ́ kejì tí ó bá dé ilé rẹ̀ Níbẹ̀ ni àwọn Ìwàrẹ̀fà yóò ti ṣe ayẹyẹ ìkọlà ojú fún òṣemàwé Egbò ilà yìí gbọdọ̀ san láàárín ọjọ́ méje tí ó jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ rí wọn lásìkò náà Lẹ́yìn ọjọ́ méje oṣù mẹ́ta wọ́n ní láti parí gbogbo ètò yìí gbogbo àwọn olóyè ni wọ́n yóò ránṣẹ́ sí láti wá kó ipa tí ó tọ́ sí ẹnìkọ̀ọ̀kan láti kó nínú ètò ìfijoyè yìí
ÌGBÉSẸ̀ KẸ́TA
Nígbà tí ó bá ku ọjọ́ méjì tí àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí yóò bẹ̀rẹ̀ àwọn olùbọ olóyè márùnún tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ekìrì Ọbalúfọ̀n Súmọ́ Sàò sanyìn àti ọlọ́jà dókò ni yóò lọ sí ilé olóyè gíga Sàsọré láti mú Òṣemàwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ sí ojúbọ tí ó wà ní ọ̀nà Èpè fún ètùtù kí wọ́n tó kúrò náà yóò ti ta aṣọ funfun mọ́ lọ́rùn Nígbà náà ni wọn yóò mu lọ tààrà sí ilé ọlọ́jàDókò tí wọ́n bá ti dé ìlú Lẹ́nu ibodè tí ó kángun níbi tí ọlọ́jàDókò tí ń dúró dè wọ́n ni yóò ti bọ aṣọ funfun ọrùn Òṣémàwe tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn
Lẹ́yìn èyí ni wọ́n yóò kẹ̀yìn sí ara wọn èyí tí ó fi hàn pé Òṣemàwé tuntun yìí kò gbọdọ̀ gbá ilé ọlọ́jà Dókò mọ́ Àwọn olùbọ olóyè yìí yóò máa mú Òṣemáwe padà lọ sí ilé olóyè gíga Sàsọré
IPA ÀTI IPÒ ÌLÚ ÒNDÓ NÍPA OGUN JÍJÀ
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ipa àti ipò Oǹdó nípa ogun jíjà Oǹdó kì í ṣe nǹkan tí a lè fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ogun jíjà Ogun jíjà ni ó sọ Oǹdó di ìlú tí ipò rẹ̀ ga ní àwùjọ Yorùbá lónìí yìí Bákan náà tí a bá wo ọba pùpùpù tí ó tẹ ìlú Oǹdó dó alágbára ni jagunjagun sì ni pẹ̀lú
Agbára akínkanjú tí àwọn jagunjagun Oǹdó jẹ́ kì í jẹ́ kí àwọn ara àdúgbò wọn le è kọ iyán wọn kéré Wọ́n máa ń fi Oǹdó sí ipò ńlá nípa èyí
Ènìyàn kò le è ni ipò tó ní láárí ní ìlú Oǹdó bí kò bá jẹ́ akọni Akọni ni ó ń di ipò mú ní ìlú Oǹdó Wọ́n sì máa ń yàn wọ́n sípò nípa ipa tí wọ́n ti kó sẹ́yìn Bí àpẹẹrẹ ọba Bàjùmù tí ó jẹ́ alákínkanjú bí bàbá rẹ̀ ó lọ sígun bá ìlú kan tí ó súnmọ́ Oǹdó nígbà tí ó gbọ́ pé wọ́n fẹ́ máa jẹ gàbalé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí
IPA ÀTI IPÒ ÀWỌN ỌBA ÌLÚ ÒNDÓ GẸ́GẸ́ BÍ ALÁGBÁRA
Àwọn ọba ìlú Oǹdó jẹ́ olórí ogun Wọ́n lágbára wọ́n sì jẹ jáde nínú oríkì wọn Oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí wọ́n gbà fi agbára hàn ló wà nínú oríkì wọn Àpẹẹrẹ èyí jẹ jáde nínú oríkì ọba òkúta
Òyán onídà
Òyanyàn nímú
Ògbogbò létí
Ó ṣe owó ọba onídà
Egún ńlá o ilà
Gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú oríkì wọn a tún rí àpẹẹrẹ agbára oògùn tí ó jẹyọ nínú oríkì ọba Lósùnlá
Ajagíjigì oògùn
Orìṣà Ẹ̀gbá kúkú
Olókè mẹ́ta
Ó sọmọ di pùyépùyé ilà
Yàtọ̀ sí agbára oògùn tí àwọn ọba wọ̀nyí ń lò wọ́n kápá àwọn ènìyàn dáadáa wọn a sì máa lo agbára àti ipò wọn lórí àwọn ènìyàn wọn Àpẹẹrẹ èyí hàn nínú oríkì Jomu
Ó pa baba wọn run
Ó pa ayé run
Ó pa onígbọ̀wọ́
Ó dá jẹ ẹran mínímíní
Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú òkè yìí Jomu tí ó ni oríkì yìí náà le ní ẹ̀dá Bákan náà agbára wọn pọ̀ dé ibì kan dé ibi pé wọn a máa fi ìyà jẹ ìjòyè ìlú wọn kò sì bẹ̀rù àjẹ́ nítorí wọ́n ní agbára
OGUN JÍJÀ
Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀rí tí a ti rí fàyọ nínú oríkì àwọn ọba yìí a tún rí ẹ̀rí mìíràn tó tún fúnka mọ́ ọn pé yàtọ̀ sí pé wọn lówó wọ́n lọ́lá wọ́n nípò wọ́n ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti rí i pé ogun kò ja àwọn ènìyàn wọn Wọ́n ní agbára láti jagun ṣẹ́gun Àpẹẹrẹ èyí ni a rí nínú oríkì ọba Àfaidùnjoyè àsìkò ọba yìí ni wọ́n lọ ṣígun bá Ìrelé ní ìgbà kejì
ọmọ ọba Arógun má tìdí
Àjànàkú sọwọ́ ìjà sókè
Ọmọ aródẹ́dẹ́ wọnú ogun
Ọmọ afẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́jẹ̀ wẹ̀
IṢẸ́ ÒÒJỌ́ WỌN
Yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń ta kókó wọn kì í fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú iṣẹ́ àgbẹ̀ ní ṣíṣe ní ìdílé wọn Wọ́n a sì máa ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú oko wọn àti pé iṣẹ́ àgbẹ̀ yìí sì máa ń sọ wọn di olówó púpọ̀
orokoroko gbọwọ́ ọ fújà
Kì í sọmọ ìbílẹ̀ lo ṣe lọ
Ó mókó nílé
Ó mú àdá nílé
Ó dágbádá wọnú oko
Bákan náà ojúlówó iṣẹ́ wọn àwọn ọba ìlú Òndó ní láti dábò bo àwọn ara ìlú Àpẹẹrẹ èyí wa nínú oríkì ọba Àpèrúwà
Ará ìjámá
Ó sékẹ̀ ará ìlú
Ó sèké Àlejò
Àlejò gbàgbé ilé
ÈTÒ ÌṢÈLÚ
Onírúurú ọ̀nà ni àwọn Òndó ń gbà ṣe ètò òṣèlú wọn Wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan yìí kí ìlú ba à lè tùbà tùṣẹ A lè rí lára ọ̀nà òṣèlú wọn
Ọba Ìbídàpọ̀ Adédìísẹwo Adésànájè ní kété tí ọba yìí gorí oyè ó ṣe àbẹ̀wò sí gbogbo agbègbè tí ó wà ní Oǹdó láti rí i pé ìfẹ́ àti àlàáfíà wà Ó rí i pé ìlú Oǹdó ń gbé ayé ìrọ̀rùn ó dá agbègbè márùndínlógún mìíràn sílẹ̀ Ijámà
Ọba yìí jẹ́ onígbàgbọ́ tí ó sin Ọlọ́run bí ó ti yẹ Àsìkò rẹ̀ ni wọn dá ìjọba Oǹdó sí méjì ìlà Oòrùn àsìkò yìí ni wọ́n gbìmọ̀ láti sọ ilé ẹ̀kọ́ gbogbońṣe di Fásitì
Olówó ni ọba Adésanoyè kí ó tó jẹ́ ọba ìlú Oǹdó olówó jaburata ni Ó kọ́ ààfin ìgbàlódé fún àwọn ará ìlú Òun ni ọba kejì tí ó lọ sí ilẹ̀ọba ÒkèÒkun
Ní kété tí ó dádé lẹ́yìn ọdún mẹ́ta ni ọmọ bíbí ìlú Oǹdó di Gómìnà ìpínlẹ̀ náà Òun ni Dókítà ọmọ bíbí ìlú Oǹdó tí ó jọba ó sì tún máa fún àwọn aláìní lówó ó sì tún fi owó rẹ̀ kọ́ ilé Ọlọ́run àti mọ́sálásí ó gbìyànjú nígbà ayé rẹ̀
Ọba yìí ṣe ohun máànígbàgbé sí Oǹdó ó fẹ́ràn ijó àti orin ìgbàgbọ́ púpọ̀ Ọba yìí kò gbà kí wọ́n fi owó du oyè mọ́ Ìgbà ọba yìí ni wọ́n kọ́ ọjà tuntun tí ó wà ní sábó Ó ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹfà fún ètò àti ìlọsíwájú ìlú Oǹdó
Ìmúra
Bákan náà a máa rí i pé ìmúra wọn jẹyọ nínú oríkì wọn
Ọmọ àfẹ́rí wọ̀wọ̀ sọrọ̀
Aji ṣówó otùn ọwọ́
Ekejì ìlẹ̀kẹ̀
Ọmọ Aládé igbó
Òjiwà jiwa ìlẹ̀kẹ̀
Bákan náà ní ìlú Oǹdó ìmúra wọn máa ń yàtọ̀ sí ara wọn Ìdí èyí ni wí pé àwọn ará ìlú yìí yóò tètè mọ̀ iru ẹgbẹ́ tí wọn wà Èyí ni à ń pè ní ìpelè ṣùgbọ́n lóde òní olóyè àti ẹni tí kò jẹ oyè máa ń múra láì mọ̀ ìtumọ̀ wọn
Èkíní Àwọn òtú máa ń fi tiwọn kọ́ ọrùn ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì yìí yóò kọjá àyà
Èkejì Àwọn ọ̀túnba wọ́n a fi aṣọ tiwọn kọ́ ọrùn ọwọ́ rẹ̀ yóò sì lọ sí ẹ̀yìn
Bákan náà ni a tún rí àkún ọwọ́ àti ti ẹsẹ̀ tí ó wà fún ọba pẹ̀lú àwọn Ìwàrẹ̀fà nìkan ṣùgbọ́n àwọn olóyè tó kù le wọ àkún sí ọwọ́ kan ṣoṣo
Gẹ́gẹ́ bí òwe ilẹ̀ Yorùbá pé ọba ló ladé orí ìlẹ̀kẹ̀ ni ti àwọn ìjòyè Ní ìlú Oǹdó àwọn olóyè máa ń fi àkún sọ́wọ́ méjèèjì ṣùgbọ́n àwọn òpójí le fi sí ẹsẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ méjèèjì Ẹni tí kò bá jẹ oyè kò gbọdọ̀ fi àkún sí ọrùn tàbí ọwọ́ Bákan náà ẹni tí kò ní ìyàwó kò gbọdọ̀ jẹ oyè
Gbogbo àwọn kókó tí a rí fàyọ yìí ni ó ṣe pàtàkì nínú oríkì orílẹ̀ àwọn ọba ìlú Oǹdó
ORÍ KARÙNÚN
ÀBÁLỌBÁBỌ̀
ÌFÁÀRÀ
Bí ọkọ bá ròkun rọ̀ṣà èbúté ni yóò gúnlẹ̀ sí Orí tí ó gbẹ́yìn iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ni a dé báyìí Gbogbo ìlàkàkà wa lórí iṣẹ́ yìí àti àríwòye tí a ni tí ó jẹyọ ni yóò jẹ́ pàtó orí yìí A ó ṣe ìsọníṣókí àbájáde ìwádìí àmúyẹ àléébù àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú
ÌSỌNÍṢÓKÍ ÀBỌ́ ÌWÁDÌÍ
Láti ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni ó ti farahàn pé ipa àti ipò pàtàkì ni oríkì ń kó láwùjọ àwa ọmọ Yorùbá Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ṣe jẹ́ ìjánú ọmọ ni oríkì jẹ́ ìtọsẹ ọmọ ènìyàn Ìlú Oǹdó ti ó jẹ́ ọ̀kan lára ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ Oǹdó ni ó jẹ́ kókó àpilẹ̀kọ yìí Ọ̀pọ́ òye àti ìmọ̀ ni àpilẹ̀kọ yìí sì ti tún mú jáde nípa ìlú Oǹdó àti oríkì ọba wọn
Lára àwọn ọgbọ́n àti ìmọ̀ tí a rí fàyọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ni pé bí oríkì ṣe pàtàkì láàárín ìran Yorùbá bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pàtàkì ní ìlú Oǹdó Èyí farahàn láti ara oríṣìí àwọn oríkì àdání àti oríkì àwọn ọba tí a bá pàdé nínú àpilẹ̀kọ yìí Lára àwọn ohun tí a bá pàdé nípa oríkì àwọn ọba yìí náà ni pé ó jẹ́ kí a mọ̀ wọn bí alágbára àti alákínkanjú ènìyàn
Bákan náà ó tún ń ṣe àfihàn àwọn àṣà tí wọ́n gùn lé nípa pé wọn máa ń ní àánú àwọn ènìyàn lójú púpọ̀ A kò ṣàì rí ipò wọn nínú oríkì a rí i pé ìṣèlú wọn tó jẹyọ nínú oríkì wọn yìí náà ni pé wọ́n máa ń jẹ oyè mìíràn yàtọ̀ sí ọba Àfihàn oríkì àdáni tún jẹyọ nínú oríkì àwọn ọba wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá ṣe ní oríkì àdáni
Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àṣà yàtọ̀ sí èyí tí a ti mẹ́nu bà lókè ni ó tún jẹyọ nínú oríkì àwọn ọba wọ̀nyí tí a bá pàdé
ÀMÚYẸ ÀTI ÀLÉÉBÙ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ
Pàtàkì ohun tí ó jẹ́ àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé ó gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá yọ Ó sì tún mú kí àwọn ohun tí ó ti ń dohun ìgbàgbé tún di àmúlò padà nílẹ̀ Yorùbá lápapọ̀ àti pàápàá ìlú Oǹdó bí àpẹẹrẹ a kì í ki oríkì mọ́ níbikíbi yálà níbi ayẹyẹ kan ni tàbí nínú ilé láti ṣe kóríyá fún ènìyàn
Lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀ ó mu kí a ní ìmọ̀ àmọ̀dájú nípa ìlú Oǹdó tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìlú Oǹdó À mọ àṣà ìṣe èèwọ̀ iṣẹ́ àwọn babańlá wọn àti oríkì àwọn ọba wọn yàtọ̀ sí èyí a tún ní àǹfààní láti ní òye àti ìmọ̀ tó dájú nípa ètò òṣèlú àti ìṣèjọba lápapọ̀ àti pàápàá ètò ẹ̀sìn àti ètò wọn láti ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ àti ibi tí ó gbòòrò dé báyìí lónìí
Láì ṣe àníàní bí a ṣe rí àmúyẹ nípa iṣẹ́ yìí náà ni a rí àléébù rẹ̀ Ọ̀kan lára àwọn àléébù náà ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn ni kò fi taratara dáhùn sí àwọn ìbéèrè tí a ń béèrè lọ́wọ́ wọn
Bákan náà àwọn mìíràn rò pé ń ṣe ni a wá láti jí àwọn ohun ìṣúra wọn kó lọ nítorí ìdí èyí onírúurú wàhálà ìdààmú àti àbùkù ni wọ́n fi kàn wà kí á tó lè rí ìwádìí díẹ̀ ṣe fún iṣẹ́ ìwádìí yìí
ÌMỌ̀RÀN FÚN IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ
Ohun tó dájú ni pé ọgbọ́n kò pin sí ibì kan Ibi tí ènìyàn bá ṣe é dé ni ó ń rí i mọ Ibi tí ènìyàn bá sì rí i mọ ni yóò sọ̀rọ̀ dé Ibi tí aṣèwádìí yìí bá a dé ni ṣíṣe àlàyé lórí oríkì àwọn ọba ìlú Oǹdó ṣùgbọ́n òye tí a tún ní ni pé ìwádìí lè dá lé ewì àbáláyé mìíràn bí i bọ̀lọ̀jọ́ àrùngbè tí ó lè fi kún ìmọ̀ wa nípa ìlú Oǹdó Yàtọ̀ sí èyí ààyè ìwádìí sì tún wá lórí oríkì àdáni àwọn ìdílé mìíràn tí wọ́n jẹ́ ìdílé olóyè yàtọ̀ sí ìdílé ọba ní ìlú Oǹdó
ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀
Láìṣe àníàní a ti ná ìgbárá a ti ná ìgboro lórí iṣẹ́ ìwádìí yìí ibi tí a bá dé rè é lórí àgbéyẹ̀wò oríkì àwọn ọba ìlú Oǹdó
Ṣáká ló dájú bí àdá pé nínú oríkì àwọn ọba ìlú Oǹdó ni a ti rí gbogbo ohun tí àwọn ọba náà àti àwọn babańlá wọn ti gbé ṣe Kò sí júu jùu tí ẹnikẹ́ni fi lè boni lójú tí a bá ka oríkì wọn akínkanjú alágbára ni àwọn ọba tí ó ti jẹ ní ìlú Oǹdó
ÀKÓJỌ ORÚKỌ ÌWÉ
Adéoyè Orúkọ Yorùbá Ìbàdàn
Adéoyè Àṣà àti Ìṣe Yorùbá
Adéyẹmí L Tíọ́rì Lítíréṣọ̀ Ní Èdè Yorùbá Ìjẹ̀bú Òde
Akinbinuade A Oríkì àti Ètò Ayé Ìlú Oǹdó
Babalọlá Ìjálá Ìbàdàn
Babalọlá A Orin Ọdẹ fún Àṣeyẹ
Babalọlá A Àwọn Oríkì Orílẹ̀ Mẹ́tàdínlógún
Babalọlá A Àwọn Oríkì Bọ̀rọ̀kìnní
Dáramọ́lá O àti Jẹ́jẹ́ A Àwọn Àṣà àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá Ìbàdàn Oníbọnòjé
Ládélé T àti Fáníyì JOO Ẹkún Ìyàwó Ìbàdàn
Ògúnbọ̀wálé PO Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá Ìbàdàn
Ọlábímtán A Àkójọpọ̀ Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ Àṣà Yorùbá Àṣà Yorùbá Ìbàdàn
Ọlátúnjí O Yorùbá
Ògúnṣínà Yorùbá Ìlọrin
Ṣówándé F àti Fágbèmí A Orúkọ Àmútọ̀runwá Ìbàdàn
Yémiítàn O Ìjálá Aré Ọdẹ Ìbàdàn
ÌṢỌWỌ́LOÈDÈ NÍNÚ ÌWÉ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀ TÍ LÁWUYÌ ÒGÚNNÍRAN KỌ
ADENẸKAN ADEṢỌLA OLUWAFUNMILAYỌ
APÁ KAN IṢẸ́ ÀṢEKÁGBÁ FÚN Ẹ̀KỌ́ ÀKÀGBOYÈ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌPÌLẸ̀ Ẹ̀DÁ Bii Eè NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ NÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ YUNIFÁSÍTÌ ÌLỌRIN ÌLỌRIN NÀÌJÍRÍÀ
OṢÙ ÈBÌBÌ ỌDÚN
ÌFỌWỌ́SÍ
Iṣẹ́ àkànṣe yìí ni a ti kà tí a sì rí i pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dáÈdè àti Èdè Nàìjíríà Yunifásítì Ìlọrin Ìlọrin
ALÀGBÀ LAYỌ̀ ÒGÚNLỌLÁ ỌJỌ́
ALÁBÒÓJÚTÓ
OLÙYẸ̀WÒ ÌTA ỌJỌ́
Ọ̀JỌ̀GBỌ́N ỌJỌ́
OLÓRÍ Ẹ̀KA Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ Ẹ̀DÁ
ÈDÈ ÀTI ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ
ÌFISỌRÍ
Mo fi iṣẹ́ àkànṣe yìí sọrí bàbá tó bí mi lọ́mọ tí ó ti di olóògbé báyìí Àlàó Adénẹ́kàn ọmọ olódò ní Ìlàrẹ́ sùn un re Àmín
Bákan náà màmá mi Olúbùkọ́lá Àbẹ̀ní Adénẹ́kàn ẹni tó ṣe gudugudu méje yààyà mẹ́fà lórí ẹ̀kọ́ mi Kí Ọlọ́run bá mi dá ẹ̀mí wọn sí kí wọn sì jẹun ọmọ pẹ́pẹ́pẹ́ Àmín
ÌDÚPẸ́
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹni tí a ṣe lóore tí kò bá dúpẹ́ bí ọlọ́ṣà kóni lẹ́rù ni nítorí ìdí èyí ọpẹ́ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí;
Ẹni àkọ́kọ́ ni Ọlọ́run ọba ọ̀gá ògo ọ̀gbàgbà tí í gba ẹni tirẹ̀ nínú ìṣòro ọba tó pa mí mọ́ tí kò jẹ́ kí ń rí ikú òjijì tí kò jẹ́ kí ń rí ìdádúró lẹ́nu ẹ̀kọ́ mi Olódùmarè ọpẹ́ ló yẹ fún orúkọ rẹ
Bákan náà ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ alábòojútó iṣẹ́ àkànṣe yìí Alàgbà Layọ̀ Ògúnlọlá fún ìfaradà àti ìyànjú tí wọ́n ń gbà mí kí iṣẹ́ àkànṣe yìí tó di títẹ̀ ẹ ṣeun mo dúpẹ́
Ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn olùkọ́ mi gbogbo bí i; Ọ̀mọ̀wé Lérè Adéyẹmí Alàgbà Adéọ̀ṣun Aya Ọ̀gbẹ́ni Ọmọ́léwu O Aya Adékẹyè Alàgbà Báre Atóyèbí Alàgbà Òkèwándé àti àwọn olùkọ́ mi tó kù Ẹ ṣé púpọ̀
Olórí ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ màmá mi nítorí Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àtiránmú gángan kò sẹ̀yìn èékánná Àwọn ni ọlọ́kọ̀ tó wà mí wá sáyé tí wọ́n tọ́jú mi láti kékeré títí di àkókò yìí Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé bàbá mi kò dúró ṣe baba ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àdúrà àti ooreọ̀fẹ́ Ọlọ́run màmá mi dúró gbọningbọnin lẹ́yìn mi wọ́n sì fi dámi lójú pé ibikíbi tí mo bá lè kàwé dé àwọn yóò rán mi nítorí ìdí èyí mo gbàdúrà pé iṣu ọmọ yóò jinná fún yin jẹ Àmín
Síwájú sí i ìdúpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi Gbogboadé Adénẹ́kàn Adéwọlé Adénẹ́kàn Adérójú Adédàmọ́lá Adésẹwà Olúwasèyí aya Sàlámì Kíkẹ́lọmọ aya Adénẹ́kàn Ràmọ́tù aya Adénẹ́kàn Olúbẹ́nà Olúbùnmi Ọlámídé Allison ẹ ṣe é púpọ̀ iwájú ni ọ̀pá ẹ̀bìtì yín yóò máa ré sí Ibi gbogbo tí ire ayọ̀ yín bá wà Olódùmarè yóò jẹ́ kí ó tẹ̀ yín lọ́wọ́
Ní àfikún ń kò gbàgbé àwọn afẹ́nifẹ́re mi gbogbo bí i; Alàgbà Adédayọ̀ Adélékè Alàgbà Ayọ̀bámi Agbànà Dèjì Adébísí Ìbítọ́lá aya Ọlákànmí Ṣẹ́gun Bámidélé Ẹ ṣé púpọ̀ Ọlọ́run yóò tún ilé àti ọ̀nà yín ṣe o Àmín
Bákan náà ọpẹ́ mi tún lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi gbogbo alábàáṣeré àti olùrànlọ́wọ́ mi gbogbo bí i Olówólayémọ̀ Ìrètíògo Onífádé Olúbùkọ́lá Sulaimon Balógun Olúfúnmibí Aṣagidigbi Òkìkíọlá Ajíbóyè Ẹ ṣé púpọ̀
Lákòótán mo dúpẹ́ lọ́wọ́ olólùfẹ́ mi fún ìfaradà ìnáwó nára ìforítì àbẹ̀wò àti ìfẹ́ tó fihàn nígbà gbogbo Ẹ ṣé púpọ̀ Ọlọ́run yóò nífẹ̀ẹ́ ẹ̀yin náà
ÀṢAMỌ̀
Èròńgbà iṣẹ́ àkànṣe yìí ni láti fi pàtàkì ìlò èdè hàn ní àwùjọ Yorùbá nípa ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ìṣọwọ́loèdè òńkọ̀wé Láwuyì Ògúnníran Òdú ni òńkọ̀wé yìí láwùjọ Yorùbá Bẹ́ẹ̀ sì ni a kò lè kóyán rẹ̀ kéré nínú àwùjọ àwọn òńkọ̀wé alátinúdá ẹgbẹ́ rẹ̀ tó kù Iṣẹ́ àkànṣe yìí yóò tú iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò nípa ìṣọwọ́loèdè òńkọ̀wé Láwuyì Ògúnníran
ÀTẸ ÀKÓÓNÚ
Àkọlé
Ìfọwọ́sí
Ìfisọrí
Ìdúpẹ́
Àṣamọ̀
Àtẹ Àkóónú
ORÍ KÌÍNÍ
ÌPILẸ̀ṢẸ̀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ YÌÍ
Ìfáàrà
Èrèdí iṣẹ́ ìwádìí
Àńfààní iṣẹ́ ìwádìí
Ibi tí ìwádìí gbòòrò dé
Ọgbọ́n ìwádìí
Ètò ìwádìí
ORÍ KEJÌ
AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN
Ìfáàrà
Èdè
Ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè
Lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè
Eréonítàn
Tíọ́rì ìṣàmúlò Tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè
ORÍ KẸ́TA
ÀGBÉYẸ̀WÒ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀
Ìfáàrà
Ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé
Ìtàn inú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀
Àwùjọ tó bí ìwé ìtàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀
Kókó inú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀
Ìlò Èdè nínú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀
Àfiwé
Ìfọ̀rọ̀dárà
Àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀
Àwítúnwí
Òwe
Àkànlò Èdè
Ọfọ̀
Orin
Àríwísí
ORÍ KẸ́RIN
ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀
Ìfáàrà
Ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí yìí
Àmúyẹ àti àmúyẹ iṣẹ́ ìwádìí yìí
Ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú
Àkójọ orúkọ ìwé
ORÍ KÌÍNÍ
ÌPÌLẸ̀ ÌṢE ÌWÁDÌÍ
ÌFÁÀRÀ
Lítíréṣọ̀ ni aṣàfihàn ìgbé ayé àwùjọ kan Èdè ni èròjà tó ṣe pàtàkì jùlọ tí àwọn oníṣẹ́ lítíréṣọ̀ ń lò; tí a bá ka ìwé lítíréṣọ̀ kan tí a sí sọ pé o dun; dájúdájú èdè inú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ dún Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀ a jẹ́ pẹ́ a kò jayò pa Tí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí oníṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ gbà lo èdè; èròńgbà ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ni láti jẹ́ kí a mọ ipa tí oníṣẹ́ ọnà lítíréṣọ̀ kó nínú ìdàgbàsókè lítíréṣọ̀ àwùjọ rẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀nà ìmédèlò
Ohun tí kókó iṣẹ́ yìí dálé ni wíwo ọ̀nà ìmédèlò òńkọ̀wé láwùjọ Ògúníran nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀
A ó wo àmúyẹ àti àléébù rẹ̀ bákan náà ni a ó wo ipò tàbí ààyè òńkọ̀wé láàrín àwọn yòókù
A pín iṣẹ́ yìí sí ọ̀nà mẹ́rin báyìí orí kìíní iṣẹ́ yìí ni a ti wo èrèdí iṣẹ́ ìwádìí àńfààní iṣẹ́ ìwádìí ibi tí ìwádìí gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àti ètò ìwádìí
Orí kejì ni aáyan ọ̀mọ̀ràn A ó sọ̀rọ̀ nípa èdè ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè lítíréṣọ̀ àti eréonítàn tíọ́rì ìṣàmúlò Tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè
Orí kẹ́ta ni a ti sọ̀rọ̀ nípa ọnà èdè tí òńkọ̀wé ṣàmúlò nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé Àwùjọ tó bí ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ìlò èdè nínú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ bí i; àfiwé ìfọ̀rọ̀dárà àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ àwítúnwí òwe àkànlò èdè ọfọ̀ orin àti àríwísí
Orí kẹ́rin iṣẹ́ yìí ni àgbálọgbábọ̀ ìsọníṣókí àbọ̀ ìwádìí àmúyẹ àti àléébù iṣẹ́ ìwádìí àti ìmọ̀ràn fún ìwádìí ọjọ́ iwájú
ÈRÈDÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ
Ìdí pàtàkì tí a fi ń ṣiṣẹ́ ìwádìí yìí ni pé ọ̀pọ̀ ìwé ni Láwuyì Ògúnníran ti kọ bí i ewì ìtàn àròsọ àti eré onítàn ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lámèyítọ́ sí ti wà lórí wọn ṣùgbọ́n kò tí sí ẹní tó ti sisẹ́ lórí ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ pàápàá jùlọ iṣẹ́ tó jẹ́ mọ́ ìmédèló òńkọ̀wé nínú ìwé náà
Yàtọ̀ fún pé iṣẹ́ yìí yóò fi kún ìmọ̀ tó ti wà nílẹ̀ yóò túbọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ipa tí ìlò èdè ń kó nínú iṣẹ́ ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀
Ìdí mìíràn ni láti mọ bí Ògúníran ti ṣe pàtàkì tó láwùjọ àwọn òńkọ̀wé Yorùbá nítorí lónìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ló wà lórí àtẹ tí kò ní lárijà kan sànan
Bákan náà àkíyèsí ti fihàn pé bí Ògúníran ṣe lọ èdè nínú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ yàtọ̀ sí bí ó ṣe lọ nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ yòókù
Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò tan ìmọ́lẹ̀ sí ìdí ti Láwuyì fi lo èdè lọ́nà tó yàtọ̀ báyìí
ÀŃFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ
Àńfààní àkọ́kọ́ ni pé iṣẹ́ yìí yóò mú iṣẹ́ akadá gbòòrò lórí ìṣọwọ́loèdè àti lítíréṣọ̀ Yorùbá lápapọ̀
Bákan náà iṣẹ́ yìí yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀gùn fún àwọn tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn tí ó fẹ́ ṣe ìwádìí lórí ìlò èdè àwọn òńkọ̀wé ìsáájú
Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ kí àwọn òńkọ̀wé mìíràn tí ó ń gbìyànjú tí wọn sì ń ṣe akitiyan láti gòkè ó lè máa ṣe àtúnṣe sí iṣẹ́ ti wọ́n náà
Iṣẹ́ ìwádìí yìí yóò jẹ́ kí ìmọ̀ wa gbòòrò sí lórí ọnà tí Láwùyì Ògúníran ń gbà fi èdè ránṣẹ́ sí àwùjọ
Síwájú sí iṣẹ́ yìí yóò jẹ́ kí a rí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrín iṣẹ́ ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè
Èyí nìkan kọ́ iṣẹ́ yìí yóò tún jẹ́ kí a mọ bí òǹkọ̀wé oníṣe ọ̀nà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ ṣe ń ṣe àkójọ àwọn èròjà rẹ̀ lọ́nà tí àwọn èdè tí ó ń fi sí akópa kọ̀ọ̀kan lẹ́nu ti yóò fi ni nńkan se pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tó fi ń hàn sí àwùjọ
IBI TÍ ÌWÁDÌÍ GBÒÒRÒ DÉ
Níwọ̀n ìgbà tó jé wí pé ìṣọwọ́loèdè nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni à ń yẹ̀wò nínú ìwádìí yìí a ó ni ni àńfààní láti tenumọ́ àlàyé púpọ̀ lórí ẹ̀dá ìtàn àti ọ̀nà tó gbà ṣe ìfìwà wẹ̀dá dípò èyí ohun tí a ó ṣe ni pé a wo ọ̀nà tí Ògúníran gbà fi èdè sí àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lẹ́nu a wo bóyà sítáì tó lò láti fi afọ̀ sí àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ lẹ́nu
Bákan náà a ó ṣe àyẹ̀wò fínnífínní nípa onírúurú èdè tí òńkọ̀wé lò a ó sí wo ipa ti ìgbé ayé òńkọ̀wé kò nínú ọ̀nà tó gbà lọ èdè rẹ̀
Àwọn òńkọ̀wé ti wa sáájú Láwuyì Ògúníran àìmọye ló ti tún wà lẹ́yìn rẹ̀ niwòn ìgbà tí iṣẹ́ wa ò ti dálé àwọn tó wà sáájú àti àwọn tó wà lẹ́yìn rẹ̀ nńkan tí a ó ṣe ni pé kí a ṣe àfiwé òńkọ̀wé yìí ìyẹn Láwuyì Ògúníran pẹ̀lú àwọn òńkọ̀wé eré onítàn àsìkò rẹ̀ pàápàá wíwo ìlò èdè wọ́n
ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ
Onírúurú ọgbọ́n ìwádìí ni a ní nígbà tí a bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìwádìí lára wọn ni síse àmúlò àwọn èròjà bí lílọ yara ìkàwé ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò wíwo Jọ́nà àti wíwo oríṣiríṣi iṣẹ́ tó tí wà sáájú
Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí a lọ ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nípa lílo rédíò àti fọ́nrán láti gba ohun sílẹ̀ A sí tún lọ oríṣiríṣi ìwé tí àwọn onímọ̀ tí kọ̀ sáájú
A lo ọgbọ́n ìwádìí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nítorí kí a lè gbọ́ òdodo lẹ́nu òńkọ̀wé nítorí Yorùbá bọ̀ wọn ni ẹnu òní kan láti gbọn pòún èyí ni pé tí a kò bá dé ọ̀dọ̀ òńkọ̀wé a kò lè mo ìdí tí o fi kọ̀wé rẹ̀ Kí a tó lọ sí ọ̀dọ̀ òńkọ̀wé a ti ṣe àtòjọ ìbéèrè wa sílẹ̀ a sí ti wa rédíò àti fọ́nrán láti fi gba ohun kalẹ̀ ṣùgbọ́n ó ṣe ni laanú wí pé orí àìsàn ni a ba abenọ ìmọ̀ wa ṣùgbọ́n o gbìyànjú nínú dídáhùn sí àwọn ìbéèrè wa Bákan náà ìwádìí tún gbé wa dé ìyàrá ìkàwé láti lọ wa àwọn ìwé tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ àti láti le fún wa ni ìmọ̀ kún ìmọ̀
ÈTÒ ÌWÁDÌÍ
Yorùbá bọ̀ wọ́n ni àasá tí kò bá ni kanún kò le ṣe é di bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni iṣẹ́ ìwádìí tí kò bá ni ètò rí Ọ̀nà mẹ́rin ni a pín iṣẹ́ àkànṣe yìí sí ni orí kìíní àwọn ohun tí a máa gbé yẹ̀wò ni yìí a ṣe ìfáàrà a wo èrèdí iṣẹ́ ìwádìí àńfààní iṣẹ́ ìwádìí ibi tí ìwádìí gbòòrò dé ọgbọ́n ìwádìí àti ètò ìwádìí
Orí kejì ni a ti sọ ohun tí èdè jẹ́ ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè lítíréṣọ̀ àti eréonítàn àti tíọ́rì ìṣàmúlò
Orí kẹ́ta ni a ti ṣe àlàyé àwọn kókó inú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ìtàn inú ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé àwọn ọnà èdè tí òńkọ̀wé ṣàmúlò bí i; àfiwé àwítúnwí ọ̀rọ̀ àyálò àkànlò èdè ìbádọ́gba gbólóhùn òwe àti àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ Bákan náà ni a tún ṣe lámèyítọ́ lórí àwọn ọnà èdè òńkọ̀wé pẹ̀lú
Orí kẹ́rin ni a ti ṣe àkójọpọ̀ àbọ̀ ìwádìí ìmọ̀ràn fún àwùjọ a tún wo àléébù iṣẹ́ yìí
ORÍ KEJÌ
AÁYAN Ọ̀MỌ̀RÀN
ÌFÁÀRÀ
Lábẹ́ èyí a wo ohun tí àwọn asíwájú ti sọ nípa èdè nípa eré onítàn Yorùbá àti nípa ìmọ̀ ìsọ̀wọ́loèdè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
ÈDÈ
Èdè ni àhunpọ̀ ìró tí àwọn ẹ̀yà ènìyàn kan ń lò láti mú kí àṣọyé àti àgbọ́yé wà láàrín ara wọn Onírúurú ẹ̀yà ènìyàn ni ó wà bẹ́ẹ̀ agbègbè tí kálùkù ń gbé yàtọ̀ sí ara wọn Ìdí èyí àwọn ẹ̀yà ènìyàn kan náà tí ó ń gbé ni agbègbè kan náà ni ó lè lo èdè tí wọn gbọ́ tí wọn sì lè sọ fún ìbáṣepọ̀ àlàáfíà
Oríṣiríṣi ènìyàn ni ó wà jákèjádò àgbáyé bí a tí rí àwọn aláwọ̀ funfun bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn aláwọ̀ dúdú wà Láàrín àwọn aláwọ̀ funfun ẹgbàà gbèje èdè ni ó wà bí a tí rí èdè faransé ni èdè Gẹ̀ẹ́sì Jámìní Látìnì Rósìá náà wà Bákan náà láàrín ènìyàn dúdú èdè pọ̀ lọ jara Bí i Haúsá Yorùbá Igbó Ẹdó ijọ́ọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
Ogún àwọn ènìyàn ni èdè èyí ti ó túmọ̀ sí wí pé ènìyàn nìkan ni Olódùmarè gbé èdè fúnun Gbogbo ohun abẹ̀mí ìyókù bí i ẹranko ẹyẹ àti ẹja kò ni èdè bí kò ṣe ariwo lásán
Ènìyàn jẹ́ elédè nítorí wí pé ó ni àńfààní láti kọ́ èdè tí ó wù ún àti ní ìgbà tó wù ú Bákan náà èyí ni ó fi jẹ́ kí ó ṣe é ṣe fún ènìyàn láti gbọ́ àti láti sọ ju èdè kan lọ Ó wà lọ́wọ́ ìfẹ́ láti kọ́ èdè àti àńfààní láti lo oríṣiríṣi èdè fún àsọyé àti àgbọ́yé
Fájẹ́nyọ́ sọ pé èdè ni ọ̀nà tí à ń gbà fi èrò wa hàn sí ayé gbọ́ Síwájú sí èdè ni ìró tí a sọ jáde láti ẹnu tàbí tí a kọ sílẹ̀ tí ó fi èrò ọ̀kan wa hàn ti o sì ní ètò tí ó sì ní ìtumọ̀ sí ẹní tí ó gbọ́ o tàbí tí ó ń kà á
Fájényọ́ tẹ̀síwàjú pé àlàyé wa lórí ohun tí èdè túmọ̀ sí yìí fihàn pé ọmọ ènìyàn ni Ẹdùmàrè jogún èdè fún Èdè ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ wọn sí yàtọ̀ gédé gédé sí ti ẹ̀dá Ọlọ́run mìíràn bí i ẹyẹ ẹranko àti àwọn abẹ̀mí mìíràn Èdè ọmọnìyàn kún a sì lè lò ó láti fi ṣàlàyé gbogbo nńkan tí a ní lọ́kàn Ìdí nìyí tí a fi ń dá oríṣiríṣi àrà sí èdè wa yálà a ń kọ ọ́ sílẹ̀ ni tàbí a ń sọ ó lẹ́nu
Adéyínkà òun náà fún èdè ni oríkì báyìí ó sọ pé
Èdè ni à lè pé ni ìlànà tí ẹ̀yà ènìyàn kan ń gbà láti fi èrò inú wọn hàn yálà nípa kíkọ́ èrò náà sílẹ̀ tàbí nípa sísọ ó jáde lẹ́nu lọ́nà tí ó fi lè yé gbogbo ènìyàn tí ó ń lọ ìlànà náà
Ajèlétí wo èdè bí i
ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí ó wà fún àsọyé láàrín àwọn ènìyàn àwùjọ kan
Adéboyèjé rí èdè bí i
ọ̀nà tàbí ìlànà kan tí àwọn ènìyàn gbá láti máa tẹ̀lé fi ronú kẹ́dùn yọ̀ tàbí ṣe àwọn nńkan mìíràn yálà nípa ọ̀rọ̀ sísọ tàbí ìwé kíkà lọ́nà tí o fi lè yé ẹní tí ó bá mọ ìlànà rẹ̀
ÌWÚLÒ ÈDÈ
Nínú àlàyé tí a ṣe ni òkè a tí rí àrídájú pé ènìyàn nìkan ni Olódùmarè jogún èdè fún fún ìdí èyí a lè pé èdè ní Ògún àwùjọ ènìyàn kò sí ohun yòókù tí Ẹlẹ́dàá dá tí ó ni èdè bí kòṣe àmì lásán èyí tí kì í yípadà
Èdè jẹ́ ohun tí a fi ń ronú tí a sí fi ń fi èrò inú wa hàn fún ẹlòmíràn yálà nípa sísọ ó jáde lẹ́nu tàbí kíkọ́ ó sílẹ̀ Yorùbá bọ̀ wọn ni ẹnu ẹní ni a fi ń sọ mi ò jẹ́ èyí ti ó fihàn pé ohun tí a rò nínú wa ni a fi èdè gbé jáde yálà ó wù wá ni o tàbí kò wù wá
Èdè ni a fi ń kọ ọmọ ní ẹ̀kọ́ ilé àti ẹ̀kọ́ ìwé
Èdè ni a fi ń ṣe ìròyìn yálà láàrín ara wa lórí rédíò tàbí tẹlifísàn Èdè ni a ń lò fún ìpolówó ọjà àti ìkéde gbogbo
Èdè ni a ń ló níbi ayẹyẹ gbogbo yálà ayẹyẹ ìgbàyọ̀nda lẹ́nu iṣẹ́ tàbí àwọn àríyá gbogbo tó kù
Lọ́rọ̀ kan èdè Yorùbá bí i àwọn èdè tí ó kù wúlò púpọ̀ nínú ẹ̀kọ́ ilé ìwà ọmọlúàbí ètò ìdárayá ètò ìlera ètò ọrọ̀ajé ìgbé àṣà ga níbi àwọn ayẹyẹ gbogbo
ÌMỌ̀ ÌṢỌWỌ́LOÈDÈ
ni orísun orúkọ fún ìmọ̀ yìí yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ àyálò láti inú èdè Gẹ̀ẹ́sì àti pé ó jẹ́ àkànpọ̀ ọ̀rọ̀ méjì Èyí ni
Ìmọ̀ tí a pè ní yìí ni àwọn kan dábàá pé kí a máa pé ni Talitiiki Gẹ́gẹ́ bí èrò Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọlábíyi yai
Ọ̀kanòjọ̀kan oríkì ni wọn fún un sé ohun tí ó kójú sí ẹnìkan lè kọ̀yìn sí ẹníkejì Ohun tí a lè fi ye pé ó fa sábàbí kò ju pé àwọn kan ń fi ojú ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ṣe òdiwọ́n nígbà tí àwọn kan ń fi ojú ọ̀rọ̀ lámèétọ́ wò ó
Ní wọ́n ìgbà tí òdiwọ́n ti yàtọ̀ dandan ni kí àgbékalẹ̀ náà yàtọ̀ Láti nńkan bí ọdún lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní ni àwọn ọmọ ilé Gíríkì ti ń kó ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè A gbo pé onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan nínú ìwé rẹ̀ ni ó ti síso lójú eégún ìmọ̀ yìí èyí ni àwọn oníṣe ọ̀nà yòókù rí tí wọn fi ń ronú bí àwọn náà ṣe lè fi iṣẹ́ ọ̀nà wọn dásí ètò ìṣèlú kóówá wọn pàápàá ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ilé Rọ́síà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kí àbá tí kálùkù ń dá lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láwùjọ wọn
ṣe àlàyé pé
Ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè ni nńkan ṣe pẹ̀lú àgbékalẹ̀ èrò tó ní ètò nínú ẹwẹ̀ ó tún ni nńkan ṣe pẹ̀lú oríṣiríṣi ọ̀nà tí a gbà láti yìí èrò yìí padà sí yálà ọ̀rọ̀ sísọ jáde lẹ́nu tàbí èyí tí a ṣe àkọsílẹ̀ síbẹ̀ àyípadà àwọn ohun èlò wònyìí sí ọ̀nà àgbàsọfọ̀ ni à lè pé ni ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè
Ohun tí ń sọ ni pé ìlànà àgbékalẹ̀ ètò èdè máa ń yàtọ̀ sí ara wọn Bí a bá sì fé ṣe àyípadà èyí máa ń jẹ́ àwòmọ́ ìmọ̀ọ́se ti ẹní kọ̀ọ̀kan ìtumọ̀ èyí ni pé ní wọ́n ìgbà ti ìrònú tàbí àgbékalẹ̀ kò papọ̀ ìṣọwọ́loèdè òjó gbọdọ̀ yàtọ̀ sí ti Aìná Èrò yìí kò yàtọ̀ púpọ̀ sí èrò; ìyapa tí òun ń sọ̀rọ̀ le ni ti ẹ̀yà lítíréṣọ̀ àti àbùdá àdání ti irúfẹ́ lítíréṣọ̀ bẹ́ẹ̀ ni Èyí nìkan kọ́ọ́ tún tọ́ka sí ìwà àdámọ̀ tó jẹ́ ti oníṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń jẹyọ nínú iṣẹ́ rẹ̀ nígbà yòówù ti a bá ṣe àyẹ̀wò iṣẹ́ bẹ́ẹ̀
sọ pé
Ìyapa tí oníṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan kúrò nínú òfin èdè nínú ààyè tó ní nígbà tó ń ṣe àgbékalẹ̀ èrò rẹ̀ Àwọn ìyapa wọ̀nyí a máa jẹyọ nínú ẹ̀ka èdè láti inú ẹ̀hun àwọn àbùdá tí àṣàyàn tí ń wáyé lójú ọ̀nà ìmédèlò
Èrò ni pé a gbọdọ̀ le fọkàn sí irú ìyapa báyìí ni àìmọ̀ye ìgbà kí a tó lè sọ o pòún pé ìsọ̀wọ́lọ èdè bẹ́ẹ̀ ni yen Ààyè sì wa fún àsàfọ̀ kọ̀ọ̀kan iṣẹ́ òun jẹ
sọ pé
Ìṣọwọ́ ṣe tó mọ afọ̀ kan ni iṣẹ́ tí a rán tó sì ń jẹyọ lóòrè kóòrè àti ọ̀nà tí a lè gba máa ṣe àyípadà fún àwọn àbùdá èdè ní pàtàkì lọ́nà ti wọ́n fi yàtọ̀ sí àwọn àbùdá mìíràn nínú ẹ̀dá èdè
Ìyapa kúrò nínú ìlànà tí ó ni bátànì tó wà ní ṣíṣeń tẹ̀lé ni gbogbo ọ̀nà ni ń tọ́ka sí tàbí ọ̀nà tí a lè gbà ránṣẹ́ nínú afọ̀ kan nípa síse àmúlò oríṣiríṣi àbùdá èdè lọ́nà tí ìtumọ̀ tàbí ìlò wọ́n yóò fi yàtọ̀ sí ìtumọ̀ wọn nínú ẹ̀dá èdè
ó sọ èrò rẹ̀ ó gbà pé
Ìmọ̀ ìsọ̀wọ́loèdè ni a ń lò láti gbé èrò ọ̀kan wa jáde sí olúgbọ́ Nígbà tí a bá mọ bí oníṣe ọ̀nà kan ṣe ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà tí ó fi yàtọ̀ sí iṣẹ́ mìíràn Èyí yóò fún wa ní òye láti mọ bí oníṣẹ́ ọnà bẹ́ẹ̀ ṣe pegedé sí nínú ìlò èdè
Ohun tó ó jẹ ẹní yìí lógún ni pé kí a mo nípa ọ̀nà tàbí ara tí afẹ̀dèsọ́nà dá nígbà tó ń ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ sọ èrò rẹ̀ nípa ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè ó gbà pé ìtumọ̀ yòówù tí a ó fún iṣẹ́ ọ̀nà àti ojú ti á ń rí kí a fi wó ó ara ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ló ti wá Ó sọ pé
Àwọn ti ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè jẹ lógún ni àwọn tó ń ronú nípa èdè àti ìlò rẹ̀ Ní pàtàkì ohun ti ìmọ̀ ìsọ̀wọ́lọèdè ń fún ìkà mó ni pé báwo la ti ṣe ṣe àgbékalẹ̀ lítíréṣọ̀ ganan irú èyí tó wù kò jẹ́ èyí sì yàtọ̀ sí ohun tí a gbé kalẹ̀ ganan tí í ṣe lítíréṣọ̀
Èrò tí ń pé àkíyèsí wa sí ní pé nígbà tí a ba fẹ́ ṣe àtúpalẹ̀ a gbọdọ̀ wo ìlò ẹ̀hun ọ̀rọ̀ ìtumọ̀ wọ́n àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tí a bá ń ṣe èyí a gbọdọ̀ lọ ìmọ̀ ẹ̀dá èdè
LÍTÍRÉṢỌ̀ ÀTI ÌMỌ̀ ÌṢỌWỌ́LOÈDÈ
Lítíréṣọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ àyálò tí a lò láti fi ṣàlàyé iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi èdè ṣe Lítíréṣọ̀ jẹ́ awòjìji àṣà wa nítorí pé wọ́n ń fí àwọn ìwà ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ àti ìrírí àwùjọ wa hàn bí i wọn tí ń jẹyọ nínú iṣẹ́ wa ojoojúmọ́
Lítíréṣọ̀ Yorùbá jẹ́ àkójọpọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ tí a fi èdè Yorùbá gbé ka orí ìrírí ìwòye àti ìgbé ayé àwùjọ láti ìran kan de orí ìran kejì Lítíréṣọ̀ jẹ́ iṣẹ́ ọ̀nà tí ó dúró bí i díńgí tí a sì ń tí inú rẹ̀ wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun èlò pàtàkì tí a lè fi ṣe àtúpalẹ̀ àwùjọ
fún lítíréṣọ̀ ni oríkì bàyí
Lítíréṣọ̀ ni àkọsílẹ̀ ti ó ṣe àlàyé àti ìgbé jáde èrò ìmọ̀lára àti ìhà tí a kọ sí ilé ayé
Ọ̀pádọ̀tun sọ pé
Lítíréṣọ̀ ni àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yálà tí a sọ lẹ́nu tàbí tí a kò sílẹ̀ ni èdè kan tàbí òmíràn láti fi ṣe àpèjúwe èrò ìmọ̀lára àti ìhùwàsí àwa ẹ̀dá nípa ilé ayé
Tí a bá wá ń sọ̀rọ̀ nípa lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè èyí ni bí òńkọ̀wé alátinúdá ṣe dára sí ara iṣẹ́ ọnà rẹ̀ tàbí bí ó ṣe fi èdè dára nínú iṣẹ́ ọnà rẹ̀ tí ó ń ran sí àwùjọ
sọ pé
Ìṣọwọ́loèdè ni ṣíṣe àyẹ̀wò afọ̀ ajẹmọ́ lítíréṣọ̀ pẹ̀lú èdè pé òun àkọ́kọ́ nínú ìtúpalẹ̀ àti kíka iṣẹ́ lítíréṣọ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé ìgbésẹ̀ inú ìmọ̀ ẹ̀dá èdè Òun àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì jù sí wa nínú kíka lítíréṣọ̀ ni èdè inú rẹ̀ òńkọ̀wé lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè
Àwọn òńkọ̀wé lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè wa dúró bí afojúunúsọ́nà wọ́n dúró bí aríran àti alásọtẹ́lẹ̀ Èyí ló máa ń mú kí lítíréṣọ̀ bá ojú ayé mú ni gbogbo ìgbà
Òńkọ̀wé alátinúdá ni ẹní tí ń fi èdè ṣe ọ̀nà ẹní tí ó ń fi ojú inú wo ilé ayé ẹní tí ń fi àròjinlẹ̀ kọ èrò rẹ̀ sílẹ̀; èyí tí ó lè jasi ewì ìtàn àròsọ tàbí eréoníṣe Iṣẹ́ ọnà tí òńkọ̀wé alátinúdá ń ṣe yìí lè sun jáde láti inú ìrírí ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ àṣà àti iṣẹ́ inú àwùjọ tí òńkọ̀wé wà Àwọn nńkan wòn yìí sí ni èròjà tí òńkọ̀wé alátinúdá máa ń bùlò bí òní òjò fún àṣeyorí iṣẹ́ ọnà rẹ̀; iṣẹ́ ọ̀nà tí òńkọ̀wé ṣe yìí ni a ń pé ní lítíréṣọ̀
Bákan náà ni òrìṣà kan wà tí ó máa ń gun àwọn òńkọ̀wé alátinúdá Èyí ni Akínwùmí Ìṣọ̀lá pé ní òrìṣà tí ń gún òńkọ̀wé Ṣùgbọ́n òrìṣà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó máa ń gún àwọn òńkọ̀wé alátinúdá òrìṣà kí nńkan ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá máa jọba ni ó gun Láwuyì Ògúnníran òrìṣà ìdẹ́kun ìwà ọ̀daràn ló gún Kọ́lá Akínlàdé àti Ọládẹ̀jọ Òkédìjí Òrìṣà kí nńkan ìṣẹ̀ńbáyé àti àṣà Yorùbá má parẹ́ ni ó gún Dúró Ládipọ̀
Òńkọ̀wé lítíréṣọ̀ àti onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè gbọdọ̀ jẹ́ ẹní tí ó ni ẹ̀bùn àti ìmọ̀ tó jinlẹ̀ tí ó sí gbòòrò nípa bí a ṣe lè lo ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ òwe àti àkànlò èdè ni ọ̀nà tí ó wuyì ni ọ̀nà tí ó lè múṣẹ́ òńkọ̀wé alátinúdá di àkàtúnkà
Bákan náà ni pé òńkọ̀wé lítíréṣọ̀ àti onímọ̀ ìṣọwọ́loèdè gbọdọ̀ jẹ́ ẹní tí ó ni ìmọ̀ nípa àṣà ẹ̀sìn àti iṣẹ́ àwa Yorùbá nítorí láti inú wọn ni yóò tí máa ṣe àmúlò èròjà fún iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀
ERÉONÍTÀN
Láàrín àwọn Yorùbá oríṣiríṣi eré ni ó wà Bí erémọdé ṣe wà ni eré ayò ọlọ́pọ́n wà; eré orin ìlù àti ijó náà wà pẹ̀lú Bí ènìyàn méjì bá jọ ń dá àpárá tàbí tí wọ́n ń ṣe àwàda eré náà ni wọn yóò sọ pé wọ́n ń ṣe Ó yẹ kí a kíyèsí wí pé ìtumọ̀ tí ó gbòòrò tí eré ni yìí kan náà ni ní nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì Nígbà tí wọ́n bá lọ ni Gẹ̀ẹ́sì láti fi tọ́ka sí eré tí a fi gbé ìtàn kalẹ̀ ó yẹ kí a mọ̀ pé àmúlò ọ̀rọ̀ náà lọ́nà ọ̀tọ̀ ni Kí àmúlò yìí ba yàtọ̀ gédégédé sí àmúlò ti gbogbo gbòò ni àwọn onímọ̀ tí ó túmọ̀ rẹ̀ sí Yorùbá fi sọ onítàn pọ̀ mọ́ eré láti túmọ̀ gẹ́gẹ́ bí eré tí ó ni tian nínú tàbí tí a fi hun ìtàn pọ̀eré onítàn
Láti inú ọ̀rọ̀ Gírìíkì ni Gẹ̀ẹ́sì pàápàá ti yá drama lò Ìtumọ̀ rẹ̀ nínú èdè gírìíkì sí ni iṣẹ́ Ìdí nìyí tí a fi lọ eré oníṣe láti túmọ̀ drama sí Yorùbá
Ó yẹ kí a tọ́ka sí i wí pé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ èdè ìperí méjèèjì yìí gbẹ́nulẹ́nu tàbí pé wọ́n wọnú ara wọn Kò sí eré onítàn ti kò ni iṣẹ́ nínú Nípa ẹ̀dá ènìyàn ni àwọn ìtàn náà máa ń dálé àtòjọ iṣẹ́ àwọn ènìyàn ni sì í máa di ìtàn Ìdí nìyí tí gbogbo eréonítàn fi jẹ́ eréoníṣe
Adédèji pé eréoníṣe ni
iṣẹ́ ìsìnnijẹ tí a ṣẹ̀dá tí ó ni àsepọ̀ pẹ̀lú àṣà ẹ̀sìn àti èdè àwọn ènìyàn kan
Oyèkàn Owómóyèlá náà kí eréoníṣe gẹ́gẹ́ bí
Eré tí à ń ṣe ni àkókò kan ti àwọn ènìyàn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ń sin àwọn kan jẹ́ nínú afọ̀ kan tí a gbé kalẹ̀ tí àwọn aṣafọ̀ kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn sí kópa nínú rẹ̀ ni èrò àti fi da àwọn òńwòran lára yá lórí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀
Kókó pàtàkì ti oríkì yìí ń tọ́ka sí ni pé òṣèré gbọdọ̀ wà kí òńwòran sí wà bẹ́ẹ̀ ni ṣùgbọ́n a lòdì sí wí pé dandan ni kí eré dá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tí ṣẹlẹ̀ rí
Ni èrò ti Ọlá Ròtìmí sọ pé
Eréoníṣe jẹ́ ìsìnjẹ iṣẹ́ kan tàbí ìsìn jẹ tí èèyàn kan Ó sì lè jẹ́ tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tí a gbé kalẹ̀ láti fi dá àwọn òńwòran lára yá
Oríkì yìí tọ́ka sí èròńgbà ìsìnjẹ láti dá òńwòran lára yá a gbọdọ̀ rántí pé ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti ìkọ́nilédé náà wa lára èròńgbà eréoníṣe pàápàá ni àwùjọ tiwa
TÍỌ́RÌ ÌṢÀMÚLÒ
Kí a tó mẹ́nu ba irú tíọ́rì tí a fẹ́ ṣàmúlò ó yẹ kí a sọ ohun ti tíọ́rì jẹ́ ni ṣókí
Adéyẹmí kí tíọ́rì báyìí
Tíọ́rì dàbí abẹfẹ́lẹ́ ìmọ̀ tí a fi ń la ìfun àti ẹ̀dọ̀ iṣẹ́ kan Tíọ́rì ni ìlànà kan tí ó jẹ jáde láti inú ìrònújinlẹ̀ tí a kà sí òótọ́ lẹ́yìn tí a dán an wò tí o sì jẹ́ òótọ́ bákan náà
Oríṣiríṣi tíọ́rì ni ó wà fún ṣíṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Lára wọ́n ni tíọ́rì ìfojúìhun wò ìhun inú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ ló ṣe pàtàkì sí àwọn agbọ̀ràn dún tíọ́rì yìí tíọ́rì ìfojú ààtòwò ohun to jẹ tíọ́rì yìí lógún jù ni iṣẹ́ ọnà inú ìwé kan Tíọ́rì ìṣègbèfábo èyí ni tíọ́rì tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ìjẹgàbalé àwọn ọkùnrin lórí àwọn obìnrin Tíọ́rì ìfojú ìtànìgbésí ayé òńkọ̀wé wò ohun tí tíọ́rì ń sọ ni pé kí a tó lè ṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ kan a gbọdọ̀ mo irú ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé bẹ́ẹ̀ Tíọ́rì ìṣọwọ́loèdè ohun tí tíọ́rì yìí máa ń wò ni ọ̀nà tí òńkọ̀wé gbà lọ èdè nínú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó fi yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn
Tíọ́rì tí a fẹ́ ṣe àmúlò nínú iṣẹ́ àkànṣe yìí ni tíọ́rì ìmọ̀ ìṣọwọ́loèdè níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ìṣọwọ́loèdè ni àwọn agbátẹrù tíọ́rì yìí máa ń wò gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ sáájú ìṣọwọ́loèdè òńkọ̀wé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni a sì fẹ́ wò pẹ̀lú Èyí ló mú wa yan tíọ́rì yìí láàyò
ORÍ KẸ́TA
ÀGBÉYẸ̀WÒ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀
ÌFÁÀRÀ
Ní abala yìí ni a ó ti wo ìtàn ìgbésí ayé òńkọ̀wé ìtàn inú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ìlò èdè òńkọ̀wé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ ÒŃKỌ̀WÉ
A bí Láwuyì Ògúnníran ní oṣù kọ́kànlá ọdún ní ìlú Ìbàdàn Abúlé Akínkúnmi ni ìlú Ìrókò ní ìjọba ìbílẹ̀ Akínyẹlá lẹ́bàá Ìbàdàn ni oko wọn Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Alàgbà Àmọ̀ó Ògúnníran Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Arábìnrin Julianah Oyèrónkẹ́ aya Ògúnníran Agboilé Arógunmásàá ní ìlú Ìbàdàn ni agboilé rẹ̀ Ẹlẹ́sìn Kírísítì ní í ṣe Ìran bàbá rẹ̀ ni ó sì máa ń jẹ Baṣọ̀run ti ìlú Ọ̀yọ́
Òrìṣà Ògún ni wọ́n ń bọ ní ìdílé Láwuyì Ògúnníran ògún ló ṣẹ́ wọ́n sílẹ̀ wọn kì í ṣe alágbẹ̀dẹ ọmọ ògún ganan ni wọ́n Gẹ́gẹ́ bí kò ti sí ọmọ Yorùbá tí kò ní oríkì ìdílé tirẹ̀ ni Mòso wọ́n máa ń kì í ní;
Àyìndé ògún
Ọmọ olóògun mòso
Ọmọ Awoyaakin
Ó bẹ̀rẹ̀ iléìwé nígbà tí ó di ọmọ ọdún mẹ́sànán ní iléìwé ti ní ìlú Ìrókò Ó tún lọ sí iléìwé Fìdítì Ó ṣe ìdánwò oníwèé mẹ́fà ó sì yege Ó sì ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ Lọ́yà kan ní Èkó gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé Ó gba oyè nínú iṣẹ́ ìròyìn ó tún di olóòtú àgbà nínú iléiṣẹ́ ìwé ìròyìn Ìmọ́lẹ̀ Òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ agbàròyìn
Láwuyì Ògúnníran tún ṣiṣẹ́ ní ìlú Èkìtì àti Iléṣà tí ó fún un ní àńfààní láti mọ àwọn ìlú wọ̀nyí Ìyàwó kan ni ó ní ó sì jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ níbi iṣẹ́ ìwé ìròyìn Ohun tó jẹ Láwuyì Ògúnníran lógún tí ó fi ń kọ ìwé ni pé láti iléìwé alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ ni ó ti máa ń ka àwọn ìwé Aláwìíyé tí olóògbé J F Ọdúnjọ kọ àti àwọn ìwé olóògbé Fágúnwà Àwọn ìwé tí ó kà yìí ni ó ṣe okùnfà ohun tó ó jẹ ẹ́ lógún tí ó fi kọ̀wé Ó tún máa ń sín àwọn Eégún Aláré jẹ tí wọ́n bá ń pe ẹ̀sà èyí ló fà á tí ìwé rẹ̀ Eégún Aláré fi dá lórí ẹ̀sà
Ìwé àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ kọ dá lórí Ìtàn bí òṣùpá ṣe lọ sọ́run ìwé yìí jáde ní iléiṣẹ́ atẹ̀wé
Àwọn ìwé rẹ̀ tó wà lórí àtẹ báyìí ni; Eégún Aláré Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Àtàrí Àjànàkú Ọ̀nà kan Ò Wọjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ìwé tí Láwuyì Ògúnníran kọ ń yí àwùjọ padà nípa jíjẹ́ iṣẹ́ tí ó rán wọn Ó kópa pàtàkì láti mú kí ìdàgbàsókè bá èdè Yorùbá Ó wà lára àwọn olùpilẹṣẹ̀ Ó tún wà lára àwọn tó gbé ìwé Yorùbá jáde Láwuyì Ògúnníran ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òńkọ̀wé mìíràn wọ́n sì jọ pa ọwọ́ pọ̀ kọ àwọn ìwé lóríṣìíríṣìí bí i; Ewì Ìwòyí
ÌTÀN INÚ ÌWÉ ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀
Eréoníṣe ajẹmọ́tàn ni ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Ìtàn tí ó hàn dé jùlọ nínú rẹ̀ ni bí Òwú Yìngbìn tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí a kọ́kọ́ tẹ̀dó lẹ́yìn odi IléIfẹ̀ ṣe tú àti ipa tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá kọ̀ọ̀kan bí Ìjẹ̀bú Ifẹ̀ Ẹ̀gbá àti Ọ̀yọ́ kó nínú pípa ìlú náà run Bákan náà ni a gbọ́ nípa bí ilẹ̀ Aláàfin Ọ̀yọ́ ṣe tú tí àwọn ìlú tó fi ń somi ara sì jàbọ́ kúrò tí òun náà sì di aláì lágbára Nínú ìtàn yìí ni a ti rí iṣẹ́ tí Ẹ̀yìnlààrò rán sí àwùjọ ọmọ Oòduà
Nínú eré Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ a rí i kà wí pé lẹ́yìn ikú Abíọ́dún Aláàfin Ọ̀yọ́ pàápàá jùlọ láyé Aólẹ̀ òwò ẹrú tún bẹ̀rẹ̀ padà ní pẹrẹwu ní IléIfẹ̀ àti agbègbè rẹ̀ àwọn Ìjẹ̀bú ni wọn sì ń ra ẹrú tí wọn sì ń tà wọ́n fún àwọn Òyìnbó Ọ̀rọ̀ òwò ẹrú tó ń gogò sí i yìí ló mú kí Olúkòyí fún Olówu àti Olúkùewu wá jíṣẹ́ Aólẹ̀ fún olówu tí ó sì rò ó wí pé kí ó mú òpin dé bá òwò ẹrú ṣíṣe Báyìí ni Òwu gbógun ti àwọn ìlú abẹ́ Ifẹ̀ ní Apòmù tí ó jẹ́ ọjà ńlá fún òwò ẹrú
Owó tí Òwu gbé yìí ló mú kí Ifẹ̀ sígun ìdí ògùngun tí Òwu sì pa àwọn Ifẹ̀ ní ìpakúpa Ìjà yìí àti ìjà gboro tó wáyé láàárín Òwu pẹ̀lú Ìjẹ̀bú lọ́jà Apòmù ni ó fa kí Àpapọ̀ ogun Ìjẹ̀bú àti Ifẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìsàńsá Ọ̀yọ́ àti Ẹ̀gbá gbógun ti Òwu tí wọ́n sì pa Òwu Yìngbìn run
Lẹ́yìn ìgbà tí ogun Òwu parí tán àlàáfíà kò padà sáàrin àwọn Yorùbá Gbogbo ayé di sánbẹsùn fapórọrí Wọ́n ń dira ogun láìsí ogun nítorí ìdágìrì ìjà Àwọn Yorùbá apá ìlà Oòrùn bí i; Ìjẹ̀ṣà Èkìtì Àkókó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ gbé ìránṣẹ́ àlàáfíà dìde láti bá àwọn tó ń jà parí ìjà kí àlàáfíà sì padà wá jọba láàárín wọn Àsìkò yìí náà ni Odùduwà yíra padà sí Ẹ̀yìnlàárò Ó kó àwọn aṣojú àwọn tí wọn lọ́wọ́ nínú ogun náà jọ Ó fi àṣìṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan hàn án Èyí tí ó ga jùlọ nínú àwọn àṣìṣe yìí ni àìro ẹ̀yìn ọ̀rọ̀ wò ìmọtara ẹni nìkan àti àìrántí alájọbí tí ó jẹ́ baba wọn
Bákan náà ni ó dá Adégbàremú tí ó jẹ́ aṣojú Yorùbá Ìlà Oòrùn lẹ́bi nítorí wí pé àwọn tí ó sojú fún tí gba àwọn àjòjì gòdògbò láàyè láti máa jọba lórí ilẹ̀ Oòduà Gbogbo àwọn aṣojú wọ̀nyí gba ẹ̀bi wọn nígbẹ̀yìn wọ́n sì gbà wí pé ilé ọlá Oòduà tí àwọn ti fọwọ́ ara àwọn wú àwọn gbọdọ̀ tún un mọ nítorí kí ọmọ Yorùbá tó tí jẹ́ ọmọ alátẹ ìlẹ̀kẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti ọmọ alátẹ àkún máa ba à di ọmọ alátẹ ọ̀rúnlá
ÀWÙJỌ TÓ BÍ ÌWÉ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀
Láàárín ọdún sí kí a tó gba òmìnira ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà abẹ́ ìjọba Òyìnbó ni Nàìjíríà wà nígbà náà Ètò ọrọ̀ajé àti òṣèlú àti ètò ìbáraẹnigbépọ̀ nígbà náà farajọ ti àwọn Òyìnbó Ṣùgbọ́n ní ọdún tí ìjọba kúrò lọ́wọ́ àwọn Gẹ̀ẹ́sì tí ó di tí àwa ara wa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nńkan ni àyípadà ti dé bá ní orílẹ̀èdè
Ní ọdún ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ nígbà náà ni ó ṣokùnfà kíkọ ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Kí àwọn ìran Yorùbá lè dẹ́kun ọ̀tẹ̀ àti ìjà àárín ara wọn àti fífi òpin sí òwò ẹrú ṣíṣe láwùjọ ló bí ìwé yìí
Ní ọdún tí òńkọ̀wé kọ ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ètò òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá burú jáì oníkálùkù àwọn ọba ìlú wọ̀nyí ló ń fẹ́ agbára àti orúkọ
Ní ọdún yìí ayé ti yípadà àsìkò yìí ni àwọn Òyìnbó amúnisìn wọ ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n sì ń ra ọmọ ènìyàn bí ẹrú ọmọ aráyé wá di mímú so bí ẹran ọmọ ìyá méjì wá ń dọdẹ ara wọn nítorí àtilà nídìí òwò ẹrú Ṣe ọmọ iná là á rán síná ni àwọn Òyìnbó tó ń ra ẹrú fi ọ̀rọ̀ náà ṣe Àwọn ọmọ Yorùbá ni àwọn olówò ẹrú tún bẹ̀ lọ́wẹ̀ láti máa bá wọn jí ènìyàn gbé Àwọn Yorùbá fààyè gba ohun tí kò tọ́ wọn wa ń gbógun tira wọn Wọ́n fi àìnísùúrù wólé ọlá wọ́n sọ ilẹ̀ tí ó yẹ kí ó kún fún oyin àti wàrà wọ́n sọ ọ́ di ilẹ̀ tó ń sàn fún ẹ̀jẹ̀ Wọ́n wà sọ àtẹ ìlẹ̀kẹ̀ wọn di àtẹ ọ̀rúnlá Ọ̀yọ́ ń yọ gbogbo ọmọ ìyá rẹ̀ sílẹ̀ Òwu ò wu mọ́ Kúrunmi di kékeré a rí àpẹẹrẹ nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀
Ogun ti tu Òwu àwọn tó fọ́lá Òwu pinnu láti má ṣe jẹ́ kí wọ́n tún Òwu kọ́ mọ́ àti láti gbẹ̀san lára àwọn ìlú tó ran Òwu lọ́wọ́ nínú ogun náà Wọ́n tú Ìkijà wọ́n tú Erunmi tí í ṣe ìlú abẹ́ Òwu tí Olówu sá lọ oi
Ní àkótán kí àlàáfíà lè jọba ní ilẹ̀ Yorùbá àti kí ìfẹ́ le wà láàárín àwùjọ ni òńkọ̀wé fifi ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ pàrokò sí gbogbo ọmọ ilẹ̀ Yorùbá káríayé pé kí ìṣọ̀kan jọba láàárín àwọn Yorùbá
KÓKÓ INÚ ÌWÉ ERÉONÍTÀN ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀
Àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì tí a fẹ́ yẹ̀wò nínú eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni ìjẹgàbalé ètò ọrọ̀ajé ètò òṣèlú ààbò ìlú ẹ̀sìn àwọn Yorùbá ìpè fún ìpadà ìṣọ̀kan
ÌJẸGÀBALÉ
Èyí ni kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì tí àwọn kókó mìíràn ṣo mọ́ A lè sọ wí pé òun ni ó kó àwọn yòókù sòdí nínú ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Ìjẹgàbalé ló lè fa kí a máa mú ọmọ ẹlòmíràn tà lẹ́rú láti lè mú kí ètò ọrọ̀ajé tẹni gbéra sọ Ìjẹgàbalé ló mú kí aṣáájú gbẹ́sẹ̀ lé ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀gbé tí wọn ń lọ mú fún ọkọ rẹ̀ lọ́fà Aṣáájú sọ̀rọ̀ ó ní;
Ìgbà yìí lo tó sehun ti mo fẹ́ fún mi Omífisáyọ̀! Wá mú obìnrin yìí lọ sílé fún mi ó ti dìyàwó mi ní tirẹ̀ ayé kan kò le yẹ̀ẹ́ oi
Bí kò bá sí ti ìjẹgàbalé ẹ̀yà kan kò ní máa gbógun tí ẹ̀yà mìíràn débi wí pé wọn a pa ìlú náà run Gẹ́gẹ́ bí àpapọ̀ ogun Ìjẹ̀bú pẹ̀lú Ifẹ̀ àti àwọn tí wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ ṣe pa Òwu yìngbìn run Èyí náà ló fa kí ìlú tí ó jẹ́ alàgàta bí Ìwó fọgbọ́n fara mọ́ Ifẹ̀ dípò kí wọn dóòlà ìjà náà Ẹ̀rù tó jọ pé ó ń ba Ìwó ni pé tí Òwu bá ṣẹ́gun Ifẹ̀ tán ewu ńlá ni fún Ìwó Èyí ìjẹgàbalé náà ló fa kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa gbìyànjú àròjàre níwájú Ẹ̀yìnlàárò
ÈTÒ ỌRỌ̀AJÉ
Ètò ọrọ̀ajé ló mú àwọn ọmọ Odùduwà gbógun tira wọn títí wọ́n fi dojú Òwu bolẹ̀ Lára àwọn ẹ̀ka ètò ọrọ̀ajé tó fa sábàbí ni òwò ẹrú ṣíṣe Àwọn Ifẹ̀ ń mú àwọn Ọ̀yọ́ lẹ́rú Wọ́n ń tà wọ́n fún àwọn Ìjẹ̀bú tí wọ́n a tún wọn tà fún àwọn Òyìnbó Mẹ́ta mẹ́ta bí iṣu ni wọn ń lé ènìyàn tà lọ́jà Apòmù Àwọn mẹ́rúmẹ́rú tilẹ̀ tún ń gba owó àgbà sílẹ̀ tí ó mú un di dandan fún wọn láti wá ẹni mú kí wọ́n ba à lè fi dí àgbàálẹ̀ tí wọn ti gbà lọ́wọ́ àwọn aláròóbọ̀ ẹrú A rí àpẹẹrẹ nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ nígbà tí aṣáájú àti Okúnnọ́wọ̀ ń dúnàdúrà lọ́wọ́ ara wọn tí Okúnnọ́wọ̀ sì wí pé;
Ó dá a mo faramọ́ ọn Só o mọ̀ pé o ti gbàgbàsílẹ̀ níjẹta? oi
Òwò ẹrú tí wọn ń ṣe lọ́jà Apòmù ló kógun Òwu ja Apòmù àti ogun Òwu bá àwọn ìlú wọ̀nyí jẹ́ ló mú kí Ifẹ̀ ṣígun láti gbẹ̀san A lè tànmọ́ọ̀n pé èrò láti dáàbò bo òwò ẹrú ló mú Ifẹ̀ ṣígun láti gbẹ̀san Èrò yìí kan náà kò ní sàìwà lọ́kàn Ìjẹ̀bú nígbà tí àpapọ̀ ogun Ìjẹ̀bú àti Ifẹ̀ dìde sí Òwu nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ Ó tilẹ̀ hàn wí pé àwọn àgbà ìjòyè Ìjẹ̀bú kan kò tún fara mọ́ ogun náà nítorí pé yóò dí ètò ọrọ̀ajé Ìjẹ̀bú lọ́wọ́ ní ọjà Apòmù A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Olówólayémọ̀ sọ pé;
Mo fi lọ wọn ọ̀pọ̀ wọ́n ló sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà búburú gbáà ni Òwu hù sí Ìjẹ̀bú lọ́jà Apòmù lọ́jọ́ ìjà búburú náà Ṣùgbọ́n kí a má ṣe ba wọn jà kí a ba a le máa ní àńfààní níná ọjà Apòmù lọ títí Ṣùgbọ́n àwa díẹ̀ kò fara mọ́ èyí pẹ̀lú èrò pé bí a kò bá jà ti a wa ń bẹ Òwu kí ó jẹ́ ka le máa nájà Apòmù èébú tí taja tẹran ó máa bú wa ni pé a fẹ́ràn òwò ju ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn wa táwọn Òwu pa lọ́jà Apòmù oi
Ètò ọrọ̀ajé tó dá lórí òwò ẹrú yìí náà ni a lè sọ pé ó mú kí àwọn Ifẹ̀ àti Ìjẹ̀bú tí wọn faramọ́ òwo náà rí ìbọn àti ẹ̀tù gbà lọ́wọ́ Òyìnbó tí àwọn ọmọ Oòduà sì bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó láti ṣekú para wọn títí wọ́n fi tú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú bí Òwu àti Ìkijà
Tí a bá tún wò ó a ó rí i pé ètò ọrọ̀ajé náà ló fa ìjà gboro tó bẹ́ sílẹ̀ láàrín Ìjẹ̀bú àti Òwu lọ́jà Apòmù Ọkùnrin Òwu kan ra ataare ogójì lọ́wọ́ obìnrin Ìjẹ̀bú dípò kí ọkùnrin yìí bá ataare dín ẹyọ kan ṣoṣo Èyí ló fa gbọ́misí iomiòtóo ibi tí wọn ti ń gbìyànjú àti pẹ̀tù sọ̀rọ̀ ni ọmọ Akọgun Òwu ti wọ̀ sáàrín wọn tí ó sì da igbá iyọ̀ Ìjẹ̀bú mìíràn nù lọ́jà Apòmù Èyí ló túbọ̀ mú kí ìjà búrẹ́kẹ Ọ̀pọ̀ Ìjẹ̀bú ló bá ìjà igboro náà lọ Ẹ̀san ìjà gboro tó ṣẹlẹ̀ ní Apòmù yìí ni Ìjẹ̀bú sọ pé àwọn ń gbà nínú ogun tí àwọn pẹ̀lú Ifẹ̀ fi pa Òwu run
A ti rí i báyìí wí pé ipa ńlá ni ètò ọrọ̀ajé kó nínú ogun tí àwọn Odùduwà gbé ti ara wọn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú ìwé eréonítàn Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀
ÈTÒ ÒṢÈLÚ
Nínú ìwé eréonítàn yìí a rí Òwu tó ń ja àwọn ìlú mìíràn lábẹ́ Ifẹ̀ àti Ifẹ̀ pàápàá lógun Ète wọn ni láti da wàrìwàrì bo ìlú tó yí wọn ká kí wọ́n ba à lè dẹni ìwárí fún Bákan náà ni ó jẹ́ pé ọ̀nà láti dá àwọn ìlú abẹ́ Ifẹ̀ lọ́kàn le ni ogun àkókò tí Ifẹ̀ gbé ti Òwu
Àsìkò yìí náà ni Ọ̀yọ́ di aláìlágbára nítorí pé gbogbo àwọn ìlú ńlá ńlá tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ ń yalọ láti lè wá òmìnira ara wọn kí wọn sì bọ́ lọ́wọ́ líle tí Aólẹ̀ fi ń mú wọn Ohun tí a kà nínú Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni wí pé Pópó Kétu àti Ìlọrin tí bọ́ lọ́wọ́ Ọ̀yọ́ Bákan náà sì ni àwọn obìnrin Ọ̀yọ́ dira ogun wọ́n fẹ̀hónú hàn wí pé kí Aláàfin dẹ́kun rírán àwọn ọmọ àti ọkọ wọn lọ sí ojú ogun Olórí obìnrin sọ̀rọ̀ ó ní;
Láyé Abíọ́dún a rójú ṣiṣẹ́ Láyé Aólẹ̀ la dàdìkalẹ̀ Láyé Arógananá lọ̀pọ̀lọ́ gbòde Abíọ́dún lọ tán ayé kọ ayé ó rójú mọ́ Gbogbo ọmọ tá a bí ló ti bógun lọ! ọ̀pọ̀ ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀gbé lọkọ rẹ̀ ń jà fitafita lójú ogun wọn kò sì lóyún sínú wọn kò sì gbépọ̀n sẹ́yìn! Ẹ tètè parí ọ̀tẹ̀ yìí; Kóníkòyí ó le rogun ọba aa oi
Èyí wà lára ìdí tí Ọ̀yọ́ kò fi lè ran Òwu lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àdéhùn tí wọn dìjọ ṣe wí pé tí ọwọ́ Òwu kò bá ká ogun tí Òwu ń jà láti paná òwò ẹrú àwọn a fọmọ ogun ránṣẹ́
Ní pàtàkì ọ̀rọ̀ bí ètò òṣèlú IléIfẹ̀ kò ṣe ní bàjẹ́ tí ti Ìjẹ̀bú náà kò ṣe ni di rádaràda àti èròńgbà bí Òwu tó jẹ́ igi ìdènà fún ètò ìṣèlú àti ètò ọrọ̀ajé wọn yóò ṣe di mímú kúrò lọ́nà jẹ wọn lógún
Tí a bá tún wo ètò òṣèlú abẹ́lé ìlú kọ̀ọ̀kan a ó rí i pé ọba kọ̀ọ̀kan kò dá ìlú ṣe Awùjalẹ̀ fọ̀rọ̀ ìlú lọ àwọn ìjòyè rẹ̀; ó jẹ́ kí wọn sọ sí ọ̀rọ̀ ogun tí wọn fẹ́ fi ja Òwu Bákan náà Ọọ̀ni fi ọ̀rọ̀ lọ Balógun àti Abọrẹ̀ tí Olówu náà sì fọ̀rọ̀ lọ Akọgun Nígbà tí a rí Aláàfin lórí àlééfà òun pẹ̀lú àwọn Ọ̀yọ́mèsì ni a rí tí wọn ń wá ìdáhùn sí oríṣìíríṣìí ìṣòro tí ó dojú kọ ìlú
ÈTÒ ÀÀBÒ
Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa ogun ó yẹ kí a lè mẹ́nuba ètò ààbò ìlú Ó hàn nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ wí pé ìlú olódi ni ìlú Òwu yìngbìn Ó sòro fún ogun láti ya lu ìlú wọn Kó dà bí wọ́n ṣe dáko sẹ́yìn odi ni wọn dáko sínú odi Ìgbà tí wọ́n jẹ oúnjẹ inú odi wọn tán tí ìyàn sì mú wọn ni ọwọ́ àwọn ọ̀tá tó tẹ̀ wọn
Yàtọ̀ sí èyí lílo odi bí ààbò lílo ohun ìjà lọ́pọ̀ lílo oògùn ọgbọ́n inú náà wà lára ohun tí a fi ń dáàbò bo ìlú ẹni Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ọgbọ́n inú ni olúwòó lò láti dáàbò bo Ìwó lọ́wọ́ Òwu Ó gba àwọn Ifẹ̀ láàyè láti kó ọmọ ogun jọ sí Adúnbíẹyẹ tí ó jẹ́ ilé Ìwó Ó jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún olówu wí pé òun kò fún wọn láàyè Ọgbọ́n tí ó ń dá ni wí pé tí Ifẹ̀ bá lè borí Òwu kò ní séwu fún Ìwó nípa Òwu Ọ̀nà ìsààbò kan ni èyí Olúwòó dáhùn ó ní;
Sọ fún olówu pé nítọ̀ọ́ọ́tọ́ ni Ìfẹ́ ń fẹ́ kí Ìwó ran òun lọ́wọ́ ṣùgbọ́n mo kọ̀ jálẹ̀ pẹ̀lú wọn Ní ti orí ilẹ̀ Ìwó tí wọn gbà fi dìgbòlu Òwu wọn kò sọ fún mi tẹ́lẹ̀ o Sàdédé ni ìròyìn náà kàn mí ku bí eégún ó ru pé Ifẹ̀ atòwu ń jà níbi tódò Ọ̀ṣun àtọ̀bà ti sàn pàdé Sọ pé mo ti gbọ́ ohun tólówu sọ o oi
Ẹ̀SÌN YORÙBÁ
Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn jẹ Yorùbá lógún Kò sí ohun tí Yorùbá ṣe tí ẹ̀sìn wọn kò ní nípa pàtàkì nínú rẹ̀
Kí àwọn Ìjẹ̀bú tó kógun lọ bá Òwu wọ́n bọ òrìṣà Ògègètielè oi Ifẹ̀ bọ Oòduà Ọ̀rànmíyàn àti gbogbo ọ̀kànlénírínwó irúnmọlẹ̀ tí ń bẹ lóòtù Ifẹ̀ Bákan náà ni Òwu rúbọ sí àwọn àgbààgbà márùnún tó wọlẹ̀ nílẹ̀ Òwu A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Àyàkokońnàkí sọ pé;
Ìwọ Oòduà máa gbọ́ọ
Ìwọ Ògún lákaayé máa gbọ́ o
Ìwọ Ọbalùfọ̀n máa gbọ́ o
Ẹ̀yin àgbà márààrún tó wọlẹ̀ nílẹ̀ Òwu;
Ògbògbóńdu Àmọ̀tàkò tó wọlẹ̀ nílẹ̀ Òwu
Olókose tó wọlẹ̀ tó detu inú igbó
Ẹẹ́kọọ́sìn Gbọ̀ńkáà tó wọlẹ̀ nígbàlẹ̀
Tó dàgbọ̀nrín abìwo ṣanṣan
Amúnimì Baralọ́rọ̀ tó dẹ̀ṣẹ tó dẹyọ́lọ́ tó ń yọ́ kiri oi
Bí ẹ̀sìn ṣe jẹ ara ìgbàgbọ́ wọn náà ni a ó lè yọ ìgbàgbọ́ nínú oògùn sílẹ̀ pẹ́kípẹ́kí ni wọ́n dìjọ ń rìn Nínú eréonítàn yìí a rí idán tí Yorùbá lè fi oògùn pa lójú ogun Ní ojú ìwé kọkànlá a rí bí Akọgun Òwu ṣe fọwọ́ ra àyà rẹ̀ tí ó sì fa ọfà Balógun Ifẹ̀ tí ó ti wọl sí i láyà yọ Bákan náà ni a rí i tí ó bẹ̀rẹ̀ sí rẹ Balógun Ìjẹ̀bú tapá tẹsẹ̀ nígbà tí ó gbé Akéréburú tí Akéréburú tẹnu bọ ọfọ̀ ó ní;
Àgbéró nikún ń gbọwọ!
Àgbéro ni sìgìdì í gbédà
Àgbéro ni tọwọ́ ẹ oi
Bí Akéréburú ṣe ń pọfọ̀ náà ni a rí i tí Awùjalẹ̀ ń ṣẹ́ èpè tí ó sì tún ń tàsẹ Gbogbo wọn ni wọ́n rántí pé ẹjọ́ là á ba oògùn rò kí a tó sà á
Àmọ́ sá bí wọn ṣe káràmásìkí ẹ̀sìn tó nínú eré yìí tí wọn fọ̀rọ̀ lọ gbogbo àwọn òrìṣà tó wọ́n kò fọ̀rọ̀ wọn lọ ifá Wọn kò sì bèèrè fún ìtọ́ni A lérò wí pé èyí ló fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe tí àwọn ìlú tó ń jara wọn lógun ṣe tí ó fi di pé àwọn ọmọ bàbá kan náà gbógun ti ara wọn Ṣùgbọ́n sá eléyìí lè jẹ́ àmọ̀ọ́nmọṣe bóyá òńkọ̀wé kò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ifá bọ ọ̀rọ̀ àwọn tí wọn ń bara wọn jà kí àṣìṣe lè wáyé kí ìtàn inú eré náà lè lọ bí ó ṣe fẹ́ kí ó lè ráyè ránṣẹ́ tí ó mú un lọ́kàn sí àwùjọ wa
ÌPÈ FÚN ÌPADÀ ÌṢỌ̀KAN
Èyí ni ibi tí Ẹ̀yìnlàárò ti kó àwọn aṣojú ẹ̀yà Yorùbá tí wọn ń gbógun tira wọn jọ Àwọn aṣojú náà ni wọ̀nyí; Ọlọ́gbọ́nilẹ̀ Ọ̀yọ́ Ọ̀mọ̀ràn Ifẹ̀ Májẹ̀ẹ́kódùnmíòdeẸ̀gbá Láké Àyàkokońnàkí ọmọ Egbèjì Òwu Olówólayémọ̀ ọmọ Awùjalẹ̀ àti Adégbáremú ọmọ Èwinílẹ̀Adó
Ẹ̀yìnlàárò tí ó ti fi yé wọn pé òun ni bàbá wọn àgbà bèèrè ìdí tí wọ́n fi ń dira ogun láìsí ogun Wọn sì dáhùn pé torí ìdágìrì tó lè fẹ́ da ọkùnrin lọ́nà ni Bákan náà ni wọ́n panu pọ̀ pé kì í ṣe ìdágìrì tó lè dé láti òde bí kò ṣe láti ọwọ́ ara ilé nítorí pé ilé ni ọ̀tá wà Èyí tọ́ka sí i pé àwọn ọmọ Oòduà ni wọ́n ń digun sí ara wọn nígbà tí ogun jíjà tilẹ̀ dàbí ẹni pé ó ti parí Aṣojú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ sí wí àwíjàre Wọ́n ń fẹ̀sùn kan ara wọn ní ọ̀kanòjọ̀kan Nígbà náà ni Ẹ̀yìnlàárò wá lahùn tí ó sì wí pé;
Èmi ni mo wo ẹ̀yìn wà tí mo sì rí i bílẹ̀ Oòduà ti bàjẹ́ tó tí mo rí i pé wọn ti fohun sọlé ọlá dahoro; tí mo sì rántí ọ̀rọ̀ àwọn babańlá wa pé àgbà kì í wà lọ́jà kórí ọmọ tuntun wọ́ ni mo ṣe pe ọlọ́gbọ́n ilẹ̀ Ọ̀yọ́ pé àwọn tó pètepèrò tí wọ́n wólé ọlá; kí wọn ó pe ara wọn jọ kí wọn ó túnlé ọlá mọ oi
ÌLÒÈDÈ NÍNÚ ÌWÉ ỌMỌ ALÁTẸ ÌLẸ̀KẸ̀
Èdè ni ohun èlò pàtàkì tí òńkọ̀wé fi ń ṣe ọnà nínú iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ wọn Wọ́n máa ń sa ọ̀rọ̀ lò wọn máa ń yán ọ̀rọ̀ lò láti fi ṣe ẹwà sí ara iṣẹ́ àtinúdá wọn Àkànlò ni èdè tí òńkọ̀wé máa ń lò tí iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ wọn ṣe máa ń wu ènìyàn lórí tí wọn máa ń fi èdè tí ó wuyì gbé òye àti ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ wọn yọ
Onírúurú bí aṣọ alágẹmọ ni àwọn ọnà èdè tí òńkọ̀wé máa ń fi ṣe ẹwà sí ara iṣẹ́ wọn Díẹ̀ lára irú ọnà èdè bẹ́ẹ̀ ni; àfiwé àwítúnwí àjùmọ̀rìn ọ̀rọ̀ ìfọ̀rọ̀dárà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
ÀFIWÉ
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ohun tí ó bá jọ ohun ni a máa ń fi wé ohun èpo ẹ̀pà jọ pósí ẹ̀líírí A máa ń ṣe àmúlò àfiwé nínú lítíréṣọ̀ kí ohun tí a ń sọ ba à lè yé ènìyàn ṣùgbọ́n ìlòèdè fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú iṣẹ́ aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ púpọ̀ Nígbà mìíràn a lè fi ohun tí a mọ̀ dunjú ní àwùjọ wé ohun tí a kò mọ̀ Bákan náà ni a lè fi ohun méjì tí a mọ̀ ní àwùjọ wé ara wọn A lè fi ohun tí ó ga wé ara wọn tàbí tí ó tóbi bákan náà rí bákan náà wé ara wọn Èròńgbà lílo àfiwé ni láti mú kí a ní òye nípa ohun tí a fi ń wé ara wọn kí ó sì lè yé àwa tí a ń kà á
A lè pín àfiwé sí ìsọ̀rí méjì kí ó ba à lè rọ̀ wá lọ́rùn láti lè ṣe àlàyé;
i Àfiwé tààrà
ii Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
ÀFIWÉ TÀÀRÀ
Èyí máa ń ní àwọn kókó méjì tí wọn dúró ní igun kọ̀ọ̀kan àwọn kókó méjì yìí gbọdọ̀ ní oríta tí wọn ti pàdé Èyí ni ohun ganan tí ó pa wọn pọ̀ Àwọn ohun méjì yìí lè kọ ojú sí ara wọn tàbí kí wọn kọ ẹ̀yìn sí ara wọn Bákan náà àwọn ọ̀rọ̀ atọ́ka inú àfiwé tààrà ni bí i
ÀFIWÉ ẸLẸ́LỌ̀Ọ́
Èyí yàtọ̀ sí àfiwé tààrà nítorí pé ó máa ń ṣe àgémọ́nu àwọn okùn ọ̀rọ̀ bí Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ohun méjì tí a fi ń wé ara wọn yìí kì í lọ tààrà Ohun tí ó pa wọn pọ̀ máa ń ní ìtumọ̀ ẹ̀dá Àpẹẹrẹ àfiwé tààrà tí a rí nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ nìyí nígbà tí Oníkòyí ń sọ̀rọ̀ ó ní;
Ọba ní bí Olówu bá kọ̀ láti dá wọn lẹ́kun Ṣàngó Aláàfin yóò kùn bí orò wà bá wọn níbẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò máa sọ ẹdun lu igi ọ̀pẹ níbẹ̀; kí ó má wà á jẹ́ pé ẹdun ààrà máa le sán lu Òwu pẹ̀lú oi
Nínú àpẹẹrẹ yìí a rí pé orò ló máa ń kù orò sì jẹ́ òrìṣà kan tí ó lágbára Èyí ni òńkọ̀wé ṣe fi Ṣàngó Aláàfin wé orò pé tí wọn ba wá bá níbẹ̀ wàhálà a ṣẹlẹ̀ Àfiwé náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Oníkòyí ń sọ
Àpẹẹrẹ mìíràn tún ni èyí tí òńkọ̀wé fi sẹ́nu agbẹnusọ ìlú ó ní;
Kábíyèsí gbogbo a kí yín Ẹ kú báyé ti dà yìí o! Àwa laṣojú gbogbo ìlú pata Wọ́n ní ká sọ fún yín pé kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní pé ká máa sọ fún yin mọ́ kí ẹ tó mọ̀ pé ayé kò gún mọ́ òde ìlú kò tòrò Ayé le koko bí ojú ẹja wọn ní kí ẹ bá wa tún ayé ṣe o Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kọjá àfaradà oi
Tí a bá wo àpẹẹrẹ òkè yìí ojú ẹja jẹ́ ohun tí ó le Èyí ni òńkọ̀wé ṣe fi bí ayé ṣe le wé ojú ẹja Agbẹnusọ ìlú ni òńkọ̀wé fi ọ̀rọ̀ yìí sí ní ẹnu láti lè fi bí ìlú ṣe le tó han òńkàwé Òńkọ̀wé rí èyí lò nítorí pé ohun tó le koko ló fi ayé wé Ìlò èdè òńkọ̀wé nínú àpẹẹrẹ yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ohun tí ó ń ṣàlàyé
ÌFỌ̀RỌ̀DÁRÀ
Èyí ni fífẹ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ lójú Ète lílọ́ èdè lọ́rùn nípa fífi kókó ọ̀rọ̀ dárà ni ó bí ìfọ̀rọ̀dárà Nínú ọnà èdè yìí a máa ń ya lára odidi ọ̀rọ̀ kan tí a ó ṣe àwítúnwí rẹ̀ ní ọ̀nà tí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò fi máa yípadà tí ìtumọ̀ rẹ̀ yóò sì máa bá a yípadà Àpẹẹrẹ tí a rí mú jáde nínú ìwé Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀ ni ti ọ̀mọ̀ràn tó sọ pé;
Wọ́n ní kikan ló kan ni wọ́n ń pè lọ́bàkan; ọbàkan ni wà nítòótọ́ Ká má jẹ́ kí tiwa ó kan ríro lo;ó ro ni wọ́n ń pè lórogún; ka má jẹ́ kí tiwa ó ro o Ẹ jẹ́ ká fara wa mọ́ra ni ká sì máa pe ara wa ní Arákùnrin mi látòní lọ oi
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí òńkọ̀wé fi àwọn ọ̀rọ̀ bí kan àti ro dárà láti gbé kókó tí ó tẹnumọ́ jáde kí ni òńkọ̀wé fi kún kan tí ó sì di kíkan nígbà tí ó fi ri tí ìyẹn náà sì di ríro òńkọ̀wé lo ọnà èdè yìí láti gbà òun tí ó jẹ ẹ́ lọ́kàn jáde Ọ̀nà tí ó sì gbà lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ohun tí ó ń sọ Kò sì tàsé ara wọn Tí a bá tún wo kókó ọ̀rọ̀ yìí a rí wí pé òńkọ̀wé fi ọ̀rọ̀ tí ó lò láti fi dárà sí ẹnu ẹ̀dá ìtàn ti ó jẹ́ ọ̀mọ̀ràn láti lè gba àwọn Yorùbá ti fi ogun ja ara wọn níyànjú àti láti lè jẹ́ kí ìṣọ̀kan jọba láàárín àwọn Yorùbá
ÀJÙMỌ̀RÌN Ọ̀RỌ̀
Nínú ọnà èdè yìí a máa ń ṣe àmúlò ọ̀rọ̀ èrò tàbí gbólóhùn méjì tí wọn kì í ya ara wọn Tí a bá ti gbọ́ ọ̀kan ni a ó máa retí èkejì A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Abọrẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ó ní;
Èyí Ọọ̀ni wí lo gbọ́ rè é ni o Ọsìnmọlẹ̀ Gbogbo èyí tó wí kárọ̀ ó rọ̀ mọ́ ọn ọmọ ọwọ́ kì í tojú ọwọ́ kú ọmọ ẹsẹ̀ kì í tojú ẹsẹ̀ ẹ́ rọ̀run oi
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí òńkọ̀wé lo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ara tí kì í ya ara wọn Àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọn lè bá ara wọn rìn nínú gbólóhùn Fún ìdí èyí ọ̀nà tí òńkọ̀wé gbà lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ara wọn ó sì bá ìṣẹ̀lẹ̀ tó lò ó pẹ̀lú mu
ÀWÍTÚNWÍ
Àwítúnwí yìí lè jẹ́ ti ẹyọ ọ̀rọ̀ awẹ́ gbólóhùn odidi ìlà tàbí ti èrò
ÀWÍTÚNWÍ ẸYỌ Ọ̀RỌ̀
A lè ṣe àmúlò ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo nígbà méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní orí ìlà kan náà ní orí ìlà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ A rí àpẹẹrẹ rẹ̀ nígbà tí Àyàkokońnàkí ń sọ̀rọ̀ ó ní;
Sọ fAláàfin yóò sì gbélé gbọ́ Ní gbogbo agbègbè yìí ta ni yóò kokà Olówu kéré kò sólúwa rẹ̀ ikú kì í sẹgbẹ́ àrùn Ṣàngó kì í sẹgbẹ́ oníbọn Akọgun Òwu ló jókòó yìí ọkùnrin làdá oi
Nínú àpẹẹrẹ yìí sẹgbẹ́ ni ẹyọ ọ̀rọ̀ tí a ṣe àwítúnwí rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí òńkọ̀wé ń sọ ni pé Aláàfin ju gbogbo àwọn ọba tókù lọ fún ìdí èyí ìlò èdè yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ó sì ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ẹ̀dá ìtàn tí òńkọ̀wé fi sí lẹ́nu
Àpẹẹrẹ mìíràn èyí tí a rí nígbà tí Balógun Ìjẹ̀bú ń sọ̀rọ̀ ó ní;
Láì níbọn láì lọ́fà mọ! Láì lóúnjẹ! Láì lólùgbèjà! Síbẹ̀ Olówu kò tùùbá! oi
Nínú àpẹẹrẹ yìí ẹyọ ọ̀rọ̀ láì ni a ṣe àwítúnwí rẹ̀ òńkọ̀wé sì lò ó láti fi ṣe ìtẹnumọ́ fún kókó tí ó fẹ́ rán s àwùjọ ni Ẹ̀dá ìtàn tí ó jẹ́ olórí ogun àwọn Ìjẹ̀bú ni òńkọ̀wé fi èdè yìí sí lẹ́nu nítorí náà ìlò èdè yìí àti ẹ̀dá ìtàn náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ara wọn
ÀWÍTÚNWÍ ODIDI ÌLÀ TÀBÍ GBÓLÓHÙN
Èyí ni ṣíṣe àwítúnwí odidi ìlà kan tàbí odidi gbólóhùn kan tẹ̀lé ara wọn A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Akéréburú ń sọ̀rọ̀ ó dáhùn ó ní;
Oníbẹ̀ńbẹ́ fìlù sí i!
Itańta rùkù ta rùkù
Itańta rùkù ta rùkù
Ẹ máa lè wọn lọ ń só
Ẹ máa lè wọn lọ ń só !!! oi
Nínú àpẹẹrẹ yìí a rí i dájú pé odidi ìlà ni òńkọ̀wé ṣe àwítúnwí rẹ̀ òńkọ̀wé fi ọ̀rọ̀ yìí ya àwòrán bí ogun Òwu ṣe ń lé ogun ọ̀tá lọ hàn wá ni Ọ̀kan lára àwọn akópa nínú ogun náà ni òńkọ̀wé fi ọ̀rọ̀ náà sí lẹ́nu èyí mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà
ÀWÍTÚNWÍ AWẸ́ GBÓLÓHÙN
Irúfẹ́ àwítúnwí yìí kì í mú odidi gbólóhùn tán abala kan lára gbólóhùn ló máa ń mú Abala kan yìí náà ni a sì máa ń ṣe àwítúnwí rẹ̀ A rí àpẹẹrẹ èyí nígbà tí Ọlọ́gbọ́n ń sọ̀rọ̀ ó ní;
Ẹ̀yin arákùnrin mi!
Oníkálùkù ó dọwọ́ọ̀ rẹ!
Ọ̀mọ̀rànIfẹ̀ ó dọwọ́ọ̀ rẹ
Ọlọ́gbọ́nỌ̀yọ́ ó dọwọ́ọ̀ rẹ;
Ọmọ Awùjalẹ̀ ó dọwọ́ọ̀ rẹ;
Ọmọ Egbáláké ó dọwọ́ọ̀ rẹ;
Ẹ wí fúnra yín ó dọwọ́ọ̀ àwa o!
Baba ti sọ̀rọ̀ ẹ jẹ́ ká gbọ́ oi
Nínú àpẹẹrẹ yìí a rí i pé apá kan lára gbólóhùn ni òńkọ̀wé ṣe àwítúnwí rẹ̀ tí ó sì jẹ́ pé ó ní kókó tí òńkọ̀wé fẹ́ kí àwọn òńkàwé rẹ̀ mọ̀ Fún ìdí èyí èdè tí òńkọ̀wé fi sí ẹ̀dá ìtàn yìí lẹ́nu ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí òńkọ̀wé lò ó fún
ÒWE
Òwe ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi àrògún àti àròjinlẹ̀ gbé kalẹ̀ láti fa ọgbọ́n yọ àti láti fún ni ní ìtumọ̀ pàtàkì A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Akọgun Òwu ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Olúwòó ó ní;
Olówu wá sọ pé ó rí bẹ́ẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ o ohun tí òun fẹ́ kí Olúwòó mọ̀ ni pé; bí a ti ń yọ̀ só là ń yọ́ gbọ́ Ina tá a dá nílé gọ̀gọ̀ rẹ̀ ń yọ lóde Másòó lòògùn má gbọ́ o Olówu ni gbogbo ìwà tOlúwòó hù lórí ọ̀rọ̀ yìí lòun mọ̀ pátápátá oi
Nínú ọ̀rọ̀ tí Akọgun sọ a rí wí pé òwe tí ó lò jẹ́ òwe tí ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ Òńkọ̀wé fi òwe yìí sí ẹnu rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó bá a mu kò lo òwe tí kò lọ pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Àpẹẹrẹ òwe mìíràn tún ni èyí tí a rí nígbà tí ọlọ́gbọ́n ń sọ̀rọ̀ ó ní;
Ìlẹ̀kẹ̀ ja sínú má ja síta; ìlẹ̀kẹ̀ já síta má já sínú ibìkan sá nìlẹ̀kẹ̀ yóò já sí? Wọn nílé ayé kò ṣe é gbé ọ̀run kò sì ṣe é lọoi
Nínú àpẹẹrẹ yìí òńkọ̀wé lo òwe yìí láti lè ya àwòrán ohun tí ó ń sọ sí wa lọ́kàn àti láti lè jẹ́ kí kókó tí ó rán sí àwùjọ di mímọ̀ fún ìran Yorùbá Èdè tí ó fi sí ẹnu ẹ̀dá ìtàn yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ nínú eré náà
ÀKÀNLÒ ÈDÈ
Àkànlò èdè ni lílo èdè lọ́nà tí ó yàtọ̀ sí bí a ti ṣe lè lò ó nínú èdè ojoojúmọ́ Ìtumọ̀ tí a máa ń bá nínú àkànlò èdè yóò yàtọ̀ sí ohun tí a bá nínú ìhun òkè A tún lè sọ pé àkànlò èdè ni ọ̀rọ̀ tàbí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí Yorùbá ń lò láti fi sọ̀rọ̀ tí wọn kò bá fẹ́ sojú abẹ níkòó A rí àpẹẹrẹ èyí nígbà tí Olówólayémọ̀ ń sọ̀rọ̀ ó ní;
Bèèrè dáadáa o Abọrẹ̀! Nítorí pé Òwu kì í ṣẹran rírọ̀ rárá o ẹran líle ni wọn Bèèrè dáadáa o oi
Nínú àpẹẹrẹ yìí òńkọ̀wé lo ọ̀rọ̀ yìí nítorí kò fẹ́ sọ ojú abẹ níkòó dípò kí òńkọ̀wé sọ pé Òwu burú ó lo ẹran líle Fún ìdí èyí èdè yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn náà
ỌFỌ̀
Ìgbàgbọ́ Yorùbá nínú agbára ọ̀rọ̀ ẹnu ló bí ọfọ̀ Ọfọ̀ ni ewì àwíṣẹ tí a máa ń lò láti pàṣẹ fún ènìyàn tàbí láti mú kí ènìyàn ṣe ìfẹ́ inú ẹni A rí àpẹẹrẹ nígbà tí Balógun Ẹgbá ń pọfọ̀ fún ogun tó fẹ́ lọ jà ó ní
Ń ó lọ ń ó bọ̀
Ń ó dé e dandan
Nítorí pé dídédídé ni tewé adé
Bíbọ̀ bíbọ̀ ni tẹ̀bọ̀yè
Ẹni bá pé ń má dé é
BỌlọ́run fẹ́ ń kò ní í bọ̀ bá aoi
Nínú àpẹẹrẹ yìí a rí pé òńkọ̀wé lo èdè tó wuyì láti fi gbé ọfọ̀ yìí kalẹ̀ ó sì ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí òńkọ̀wé lò ó fún nínú eré náà Bákan náà tún ni pé gbogbo ọfọ̀ tó jẹyọ nínú eré náà ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ibùdó ìtàn
ORIN
Aṣàfihàn àwùjọ ni orin jẹ́ a kì í dédé kọrin ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ibi tí ènìyàn bá wà ni yóò sọ irú orin tí ènìyàn lè kọ A rí àpẹẹrẹ orin nígbà tí Akọgun Òwu ń kọrin ní ojú ogun ó ní;
Akínjọbí ọmọ Ajíbọ̀sìn